Alawo to ba yọ ohunkohun lara mi lẹyin ti mo ba waja yoo ku tẹle mi – Olubara tilu Ibara ju bọmbu ọrọ jade - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 11, 2023

Alawo to ba yọ ohunkohun lara mi lẹyin ti mo ba waja yoo ku tẹle mi – Olubara tilu Ibara ju bọmbu ọrọ jade


Olubara tiluu Ibara, Ọba Jacob Ọmọlade ti sọ pe alawo yoowu to ba gbiyanju lati yọ ẹya ara oun, lẹyin toun ba tẹri gb’aṣọ yoo ku tẹle oun, nitori pe oun ti kilọ fun wọn. 
 
Kabiyesi naa lo sọrọ naa laipẹ yii ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu akọroyin ileeṣẹ iwe iroyin PUNCH niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun
 
Ọba Ọmọlade sọ pe nigba toun gba ade, wọn sọ pe koun wọnu ẹgbẹ okunkun, ṣugbọn oun kọ jalẹ, ati pe ọrọ ọhun di wahala, to mu koun fẹẹ fi ipo ọhun silẹ, to si ni wọn pada gba f’oun.
 
Siwaju sii lo ni awọn alawo naa leri pe oun ko le lo to ọdun meji koun too ku danu, eyi lo mu koun bẹrẹ aawẹ ati adura lati jagun, to si loun dupẹ wi pe oun pada bori agun naa.
 
Kabiyesi sọ pe ka to o ri osu diẹ si asiko yii, oun yoo ṣe ayẹyẹ ọdun mọkanlelọgbọn lori ipo naa. O ni ileri Oluwa ṣẹ ninu aye oun, nitori pe oun ko gba awọn oriṣa ati iṣẹ awo laaye ninu lori itẹ oun.
 
Ninu ọrọ rẹ, Kabiyesi ṣalaye pe:
 
“Ni kete ti wọn ṣe ayẹyẹ dide ade fun mi, awọn oloye pe mi, wọn si ni idaji ọna ni mo ṣi de pẹlu awọn aṣa ibilẹ, ati pe ohun to ku ni pe ki wọn mu mi wọnu ẹgbẹ okunkun, ṣugbọn mo sọ pe rara tori pe baba mi gan an, ẹlẹsin Kristẹni ni, mo si fẹẹ tọ ipasẹ rẹ nitori pe o ni anfani tirẹ lati jẹ ẹni to n sin Ọlọrun, kii ṣe ni ti ẹsin Kristẹni nikan.
 
“Koda too ba jẹ ẹlẹsin Musulumi, wa a bọwọ fun Ọlọrun. Ọlọrun kan naa la n sọrọ rẹ. Ta lo mọ ẹni ti yoo lọ sọrun? Ti awọn araalu lo yẹ ka maa ro. Mo kọ jalẹ nigba naa, ṣugbọn nigba ti wahala si fẹẹ pọ ju, mo fẹ kọ ilana naa silẹ, mo ko ẹru mi, mo si sọ fun iyawo mi pe a ni lati pada lọ si Ekoo, tori pe mi o le sin oriṣa.
 
“Wọn sọ fun mi loju koro koro wipe mi o ni lo to ọdun meji lori itẹ, ṣugbọn mo pa wọn ti. Mo bẹrẹ si ni gbadura ati aawẹ, bẹẹ si ni Alufa ijọ mi wa si ile mi ti a jọ ṣinu awẹ.
 
“Igbesẹ wọn ko dẹru ba mi tori mo mọ wi pe bi ile aye ṣe ri niyẹn, ninu ki o la odo kọja tabi ki o ba omi lọ, ọkan ni waa mu.
 
“Bi ọba ba waja, wọn yoo mu ọkan lara ẹsẹ rẹ, wọn yoo sin in si oju ọna to lọ si ilu naa, wọn a sin ẹsẹ keji si ọna ibomiran to ba wọ ilu ọhun, ati pe o ṣeeṣe ki wọn sin ori rẹ si Aafin. Ijọba ti dawọ eyi duro nitori pe wọn gba pe aye ti laju ju bẹẹ lọ.
 
“Bẹẹ ba wo bi wọn ṣe sin Alaafin Ọyọ, o ya mi lẹnu, wọn gbe e jade, awọn Musulumi kirun sii lara, wọn si gbe e lọ si ibi itẹ lati sin in. Wọn o ba ma gba iru eyi laaye, laye atijọ ati pe bayii, igba ti yi pada ṣugbọn a ṣi ni awọn alawo laarin wa o.
 
“Mo ti sọ fun lara awọn oloye mi, mo si ti kilọ fun wọn wi pe ẹnikẹni to ba ge ara mi nigba ti mo ba lọ tan, tabi ẹni to ba dan idankudan wo yoo tẹle mi lọ ọrun ni.
 
“Bi mo ba papoda, mo fẹ ki wọn gbe mi lọ si ibi itẹ to wa fun gbogbo eeyan, mo ti ra aye mi sibẹ, wọn ti gbẹ ilẹ naa, ti iyawo mi ko jina si temi nitori naa mo ti gbẹ ilẹ ti tọdọ mi awọn kan si ti ri i”. 
 
“Mo ti kilọ fun gbogbo wọn ṣaaju pe ẹni to ba ṣe nnkan ibilẹ yoo tẹle mi, mo si n sọ eyi daju daju. Bi adura mi yoo ba jẹ itẹwọgba tabi ko ni jẹ, kii ṣe ẹjọ ẹnikẹni, tori bi mo ba ṣe rere laye, yoo dara fun mi”.
 
Siwaju sii ni Kabiyesi sọ pe oun faramọ ofin ti ijoba ipinlẹ Ogun ṣẹṣẹ bu ọwọ lu wi pe ki wọn maa sinku awọn ọba alaye ni ilana ẹsin ti wọn ba n sin nigba ti wọn ba wa laye, idi ree to fi loun ti bọ ninu ohun to n ba oun lẹru tẹlẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI