Usman pokunso lẹyin oṣu mẹrin to ṣegbeyawo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 10, 2023

Usman pokunso lẹyin oṣu mẹrin to ṣegbeyawo


Bọwale Mumin, Ilọrin
 
Kayeefi nla gba a ni iṣẹlẹ ọhun ṣi n jẹ titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, iyẹn lori baale ile, ẹni ọgbọn ọdun kan, Usman Sani Goga ṣe gbẹmi ara rẹ lojiji nipa pipokunso.
 
Ọjọru tii ṣe Wẹsidee, ọsẹ yii ni wọn sọ pe Usman, ẹni to yan iṣẹ ayaworan laayo deedee pokunso sinu yara ibusun rẹ, lai mọ ohun fa a titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni Usman lo gbe iyawo rẹ jade kuro nile ni nnkan bii aago meji ọsan ọjọ naa, to si ṣeleri wi pe oun yoo pada lọ gbe e, ṣugbọn ti ko mu ileri rẹ ṣẹ.
 
Agbegbe kan ti wọn pe ni Akula Quarters, ijọba ibilẹ Babura, ipinlẹ Jigawa niṣẹlẹ ọhun ti waye gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
Iyawo Usman to ṣalaye f'awọn akọroyin sọ pe nigba to to asiko lati lọ sile, oun pe ọkọ oun lati wa a gbe oun. O loun pee fun igba pupọ, ṣugbọn ti ko gbe e.
 
O nigba toun ko gburo rẹ, lo jẹ koun lọ wọ mọto pada sile, to si jẹ pe iyalẹnu ni nnkan toun foju ri.
 
Obinrin naa sọ pe kayeefi lo jẹ foun nigba toun dele ni nnkan bi aago marun-un aabọ irọlẹ, toun si ba ọkada ọkọ oun  niwaju ita. O loun kan ilẹkun titi, ṣugbọn ko sẹni to da oun lohun.
 
Idi ree to loun fi ranṣẹ pe ọlọkada kan lati ba oun ja ilẹkun. O ni boun ṣe ja ilẹkun naa wọle, o ṣe oun ni kayeefi lat ba oku ọkọ oun labẹ faanu, to ti gan pa sibẹ.
 
Agbẹnusọ fun ẹṣọ aabo-ara-ẹni-laabo-ilu ti a mọ si Sifu Difensi, CSC. Adamu Shehu to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe nipaṣẹ iranlọwọ awọn ara adugbo ati awọn oṣiṣẹ aabo lawọn fi ja oku Usman bọ silẹ, to si ni ọsibitu ti wọn gbe e lọ ni wọn ti fidi rẹ mulẹ wi pe ẹlẹmin ti gba a.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI