Awọn agbebọn tun ti ji Kabiyesi ati olori rẹ gbe o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, June 20, 2023

Awọn agbebọn tun ti ji Kabiyesi ati olori rẹ gbe o


Awọn agbebọn kan ti ko tii sẹnikẹni to mọ titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii la gbọ pe wọn ti ji Ọba iluu Idọfin, Ọba Shedrack Durojaye Obibeni ati olori rẹ gbe.
 
Opopona Makutu si Idofin to wa ni ijọba ibilẹ Yagba East, ipinlẹ Kogi la gbọ pe wọn ti ji awọn mejeeji gbe salọ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.
 
Irọlẹ ọjọ naa la gbọ pe wọn da Kabiyesi ati olori rẹ lọna, ti wọn si koju ibọn si wọn, ko to di pe wọn ko awọn mejeeji wọnu igbo lọ.

Nigba to n f'idi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ naa, SP William Aya, sọ pe igbesẹ ti n lọ lọwọ lati rii pe awọn ri Kabiyesi ati olori rẹ gba jade kuro lahamọ awọn amookunṣeka naa.
 
Aya sọ pe, ọga awọn, Hakeem Adeṣina Yusuf, to jẹ ọga ọlọpaa ipinlẹ naa ti ko awọn ọlọpaa sita, pẹlu iranlọwọ awọn fijilante lati rii pe ọwọ tẹ gbogbo awọn to lọwọ si iwa buruku naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI