Baba arugbo d'awati l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 20, 2023

Baba arugbo d'awati l'Ekoo


Baba agbalagba ti ẹ n wo yii la gbọ pe awọn mọlẹbi rẹ ṣi n wa titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii. A gbọ pe lati ọjọ mẹrinlelogun, o'su karun-un, ọdun yii ni baba naa ti jade nile, ti ko si pada.
 
Goddey Ibama, lorukọ rẹ, agbegbe Ẹgbẹda ni baba yii n gbe n'ipinlẹ Ekoo.
 
Iyawo baba yii, Maryam Ibama, sọ pe ọmọ bibi ipinlẹ Rivers ni ọkọ oun, ati pe inu oṣu kin-in-ni, ọdun 2023 ti a wa yii ni wọn daa duro lẹnu iṣẹ.
 
O ni ibi iṣẹ ti wọn ti da ọkọ oun duro lo lọ lọjọ naa, lati beere owo ti wọn ṣeleri lati fun un, lẹyin ti wọn daa duro, ṣugbọn to ni alọ ni wọn ri, wọn ko ri apadabọ rẹ titi di asiko yii.
 
Iyaale ile naa sọ pe nnkan bi aago meje aarọ ni ọkọ oun jade nile, ati pe ko mu foonu rẹ dani, nitori to ti bajẹ, to si latigba naa lawọn ti n wa a.
 
O lawọn ti fi to ileeṣẹ ọlọpaa ẹka Ikẹja leti, koda, to ni pasitọ kan ti gba ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira lọwọ oun lati ba oun gbadura bi ọkọ oun yoo ṣe pada sile, to si ni pabo lo ja si.
 
Ẹnikẹni to ba mọ ibi ti baba yii wa, ko tete fi to ileeṣẹ ọlọpaa, tabi iyawo baba naa, Arabinrin Ibama leti lori foonu 08060237891, 08081932888.
 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI