Baagi, Bata, Aṣọ ni Damilọla fi gba aadọjọ miliọnu naira lọwọ ọgọrun-un eeyan lori Fesibuuku - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, June 4, 2023

Baagi, Bata, Aṣọ ni Damilọla fi gba aadọjọ miliọnu naira lọwọ ọgọrun-un eeyan lori Fesibuuku


Ariwo nla lo sọ nigba iroyin naa jade sita wi pe ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Niger ti tẹ ọmọbinrin arẹwa kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Akinnowonu Damilọla Victoria, ẹni ti wọn lori ikanni ayelujara lo ti n lu awọn eeyan ni jibiti owo ati dukia.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni awọn ti ko din ni ọgọrun eeyan ni Damilọla lu ni jibiti owo to to aadọjọ miliọnu naira lori ikanni ayelujara, to si na papa bora.
 
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Wasiu Abiọdun to gbe iroyin ọhun sita lọjọ Ẹti, Furaidee to kọja yii ṣalaye pe niṣe ni Damilọla tan awọn onibara rẹ to ti gba owo lọwọ wọn wi pe awọn kọsitọọmu ti gba ẹru oun.
 
O ni lati ile ẹjọ Majisireeti to wa niluu Minna ni wọn ti gbe ẹjọ naa wa ba wọn lọjọ kejilelogun, oṣu karun-un, ọdun yii wi pe ẹnikan to n jẹ Akinniwonu Damilọla Victoria lu awọn kan ni jibiti lori ayelujara, ati pe ọmọ ọdun mẹtalelogun to n gbe ladugbo Kọlawọle Tunga niluu Minna ni.
 
Loju ẹsẹ lo sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii, ti ọwọ si tete tẹ Damilọla nipa iranlọwọ awọn mọlẹbi ẹ. O ni lasiko ti wọn n fọrọ wa a lẹnu wo lo jẹwọ pe ori ayelujara loun ti n ta ọja oun, nipasẹ ikanni kan toun ba pade lori fesibuuku.
 
O nibẹ loun ti n fi awọn baagi, bata, aṣọ, foonu, kọmputa alagbeka ati awọn nnkan miran to n lo ina han awọn onibara oun lati ra. Nibẹ lo ti sọ pe oun ri awọn eeyan ti wọn n san owo ọja.
 
Damilọla sọ pe nigba t'awọn eeyan bẹrẹ sii sọ pe ọja oun ha, lo jẹ koun maa gba owo lọwọ awọn miran, toun si n ja owo naa walẹ f'awọn kan.
 
O leyi lo da wahala silẹ foun, toun ko fi ri ọja awọn kan gbe silẹ. Idi ree to loun fi purọ pe awọn kọsitọọmu ti gba ọja lọwọ oun, ti wọn si ni koun lọ mu owo wa.
 
Funra rẹ lo jẹwọ pe awọn onibara ti ko din ni ọgọrun-un loun gba owo lọwọ wọn, ti owo naa si jẹ aadọjọ miliọnu naira.
 
Lọwọlọwọ bayii, agbẹnusọ ọlọpaa, Abiọdun ti jẹ ko di mimọ pe awọn ti ko din ni mejilelaadọrin ninu awọn ti Damilọla lu ni jibiti lo ti yọju lati jẹrii, to si ni nigba ti iwadii ba tubọ pari, Damilọla yoo pada foju ba ile-ẹjọ.

Damilọla ree, ati orukọ ileeṣẹ to fi n lu jibiti






No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI