Saheed Anini wọ ṣọọṣi lati ji foonu, lo ba gbagbe sun lọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 3, 2023

Saheed Anini wọ ṣọọṣi lati ji foonu, lo ba gbagbe sun lọ


Ọrọ buruku toun tẹrin nigba ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun n foju ogbontariji adigunjale foonu kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Saheed Abioye, ẹni tọpọ mọ si Saheed Anini, nigba to n sọ bi ọwọ ṣe tẹ ẹ.
 
Iṣẹ awakọ la gbọ pe Saheed Anini n ṣe niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, bẹẹ naa lo tun n lo anfaani rẹ lati maa fi jalle foonu lẹgbẹ kan, iṣe to loun ti bẹrẹ tipẹ.
 
Laipẹ yi ni ileeṣẹ ọlọpaa foju awọn afurasi ọdaran han f'awọn akọroyin nipinlẹ naa, nibi ti Saheed Anini naa ti wa lara wọn. Nibẹ lo jẹwọ, to si ṣalaye bi ọwọ ṣe tẹ ẹ.
 
Nigba to n sọrọ, Saheed sọ pe ọwọ awọn ọlọpaa to n gbogun ti iwa ẹgbẹ okunkun lo tẹ oun, lakoko toun n lọ sile. O loun ṣẹṣẹ de lati ilu Ibadan ni, toun si fẹ wa a wo ọmọ oun to n gbe lọdọ mọlẹbi oun niluu Oṣogbo.
 
O ni koun too lọ wo ọmọ naa, oun gbiyanju lati ya ni ṣọọṣi kan lagbegbe Alekuwodo, nibi ti iṣọ oru ti n lọ lọwọ, pẹlu erongba lati ji foonu nibẹ.
 
“Nnkan bi aago mọkanla ku iṣẹju mẹẹdogun  ni mo de ṣọọṣi naa, ti mo si n reti igba ti yoo dara fun mi lati ji foonu awọn ba fẹẹ gba igba ijọba sinu foonu wọn. Ẹyin ṣọọṣi naa ni mo jokoo si, lati maa woye.
 
“O ṣeni laanu pe mi o ri foonu kankan ji lọjọ naa, nitori pe ṣe ni mo gbagbe sun lọ lakoko iṣọ oru naa, mi o si ji titi ti wọn fi pari ni nnkan bi aago mẹta oru.
 
“Nigba ti mo maa ji, wọn ti pari iṣọ oru, awọn eeyan si ti n gba ile wọn lọ, bi emi naa ṣe kuro niyẹn. Mi o lanfaani lati ji ohunkohun nibẹ rara.
 
“Bi mo ṣe de agbegbe Alekuwodo to wa nitosi ọja Akindẹkọ, mo ri mọto awọn ọlọpaa ti wọn n gbogun ti iwa ẹgbẹ okunkun, iyẹn ti ẹkun Dugbẹ l'Oṣogbo. Wọn da mi duro, wọn si beere ohun to wa lara mi. Mo yọ kaadi idanimọ ati apo owo mi sita fun wọn.
 
“Wọn yẹ ara mi wo, wọn ko si ba ohunkohun nibẹ. Wọn wa pada mu mi lọ si ṣọọṣi naa lati le fidi rẹ mulẹ boya ibẹ ni mo ti n bọ lootọ, ṣugbọn pasitọ naa sọ pe oun ko mọ mi ri, idi ree ti wọn fi gbe mi lọ teṣan wọn ni Dugbẹ.
 
“Igba to ya, wọn ya fọnran mi, wọn sii fi ranṣẹ sawọn eeyan wọn. Awọn to da mi mọ lo sọ fun wọn pe foonu ni mo n jigbe kaakiri, ati pe wọn ti mu mi ri. Mi o kii ji mọto, bẹẹ ni mi o kii ji ọkada, yatọ si foonu ti mo mọ nipa ẹ.”
 
O wa fidi rẹ mulẹ pe foonu ti ko din ni mejidinlogun loun ti jigbe lagbegbe ọtọọtọ nipinlẹ naa.
 
Agbẹnusọ fawọn ọlọpaa ipinlẹ naa, Yẹmisi Ọpalọla, nigba o n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe awọn yoo foju Anini ba ile ẹjọ lẹyin ti iwadii ba tubọ pari.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI