Banki Agbaye gbe oṣuba kare fun ijọba Kwara lori eto-ẹkọ, lanfaani ọtun ba tun wọle fun wọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, June 22, 2023

Banki Agbaye gbe oṣuba kare fun ijọba Kwara lori eto-ẹkọ, lanfaani ọtun ba tun wọle fun wọn


Anfaani ọtun miran lo ti wọle fun ijọba ipinlẹ Kwara pẹlu bi banki agbaye ṣe gbe oṣuba kare fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq t'ipinlẹ naa lori ọna ti wọn n gba mu ilọsiwaju ba eto ẹkọ.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ajọ kan labẹ iṣakoso Banki agbaye, iyẹn Adolescent Girls Initiative for Learning and Empowerment (AGILE) ni wọn gbe oṣuba rabandẹ fun Gomina AbdulRazaq nipa iranwọ to n 
ṣe f'awọn akẹkọọ, paapaa awọn ọmọde kaakiri ipinlẹ naa.

Ajọ AGILE jẹ eyi ti banki agbaye n ṣagbatẹru rẹ, nipa iranwọ ijọba apapọ Naijira.
 
Ni bayii, a gbọ ipinlẹ Kwara naa ti wa lara awọn ipinlẹ ti yoo maa jẹ anfaani iranlọwọ fun ilọsiwaju eto ẹkọ to rọrun f'awọn akẹkọọ, paapaa awọn akẹkọọbinrin, lawọn ile-ẹkọ, paapaa julọ, ile-ẹkọ girama.

Alakoso agba ajọ naa lẹka ileeṣẹ to n ri sọrọ eto ẹkọ lorileede Naijiria, Hajia Aminah Haruna nigba to n sọrọ laipẹ yii niluu Ilọrin, sọ pe awọn ti ri akitiyan ipinlẹ Kwara lori eto ẹkọ, to si loo di dandan lati dide iranwọ, nitori pe ọrọ eto ẹkọ awọn ọmọde lo jẹ wọn l'ogun.

Siwaju lo ni awọn maa n lo ipa awọn eeyan, ajọ ati ijọba lori ọrọ eto ẹkọ, eyi to maa n mu k'awọn gboriyin f'awọn to ba n ṣe daadaa.
 
O l'awọn ti lọ kaakiri lati wo awọn ile-ẹkọ to wa n'ipinlẹ Kwara, t'awọn si rii pe agbegbe ikẹkọọ to ba ti igbalode mu l'awọn akẹkọọ n jẹ anfaani rẹ, to si lo jẹ iwuri pupọ.
 
Ọkan lara awọn alẹnulọrọ lẹka eto ẹkọ fun banki agbaye, Tunde Adekọla, nigba toun naa n sọrọ jẹ ko di mimọ pe awọn wa si ipinlẹ Kwara lati wo o boya yoo wa lara awọn ipinlẹ mọkanla ti wọn tun n foju sọna fun lati ko mọra fun eto AGILE, to si l'awọn ti ri ipa rere di mu nibẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI