FADAMA NG-CARES: Ẹgbẹrun mẹjọ agbẹ tun bọ saye ni Kwara n'ipele keji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 22, 2023

FADAMA NG-CARES: Ẹgbẹrun mẹjọ agbẹ tun bọ saye ni Kwara n'ipele keji


Lojuna lati mu igbayegbadun f'awọn araalu, ati ọpọ ounjẹ laaarin ilu, eyi ti yoo din iṣẹ ati oṣi ku lawujọ, ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq loun ti ṣetan dide iranwọ f'awọn agbe ni ipele keji FADAMA NG-CARES, eyi ti wọon bẹrẹ ni nnkan bi ọdun meloo sẹyin.
 
Awọn agbẹ ti ko din ni ẹgbẹrun mẹjọ kaakiri ipinlẹ naa la gbọ pe wọn yoo gba awọon ohun ọgbin ati irinṣẹ ti yoo mu ki iṣẹ agbẹ ti wọn dawọle rọrun.

Igbesẹ yii la gbọ pe o ti bẹrẹ latigba ti ajakalẹ arun Korona ti bẹrẹ, to si mu ki ijọba maa wa ọna lati dide iranwọ f'awọn araalu kaakiri ipinlẹ naa, ti yoo mu nnkan rọrun.
 
Kaakiri ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa n'ipinlẹ Kwara ni iroyin fi to wa leti wi pe awọn agbẹ yoo ti jẹ anfaani owo iranwọ ti ajọ FADAMA ṣagbatẹru rẹ pẹlu ajọṣepọ ijọba Kwara.

Nigba to n sọrọ laipẹ yii, alakoso eto Fadama NG-CARES nipinlẹ naa, Omimọ-ẹrọ Busari Toyin Isiaka, yoo lọ jinna nitori pe afojusun rere lawọn n reti nipa ọpọ ounjẹ.
 
Onimọ-ẹrọ Isiaka ṣalaye pe eyi gan-an yoo tun mu irọrun ba bi owo ori epo rọbii ṣe lọ soke laipẹ yii, ti yoo si jẹ ki ounjẹ pọ rẹpẹtẹ pọ laaariin ilu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI