Iranlọwọ Gomina AbdulRazaq lo n mu wa tẹsiwaju - Awọn alakoso ile-ẹkọ ọkọ ofurufu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 22, 2023

Iranlọwọ Gomina AbdulRazaq lo n mu wa tẹsiwaju - Awọn alakoso ile-ẹkọ ọkọ ofurufu


Bi ile-ẹkọ ọkọ ofurufu to wa niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, Ilorin Aviation College ṣe ṣayẹyẹ ikẹkọọjade f'awọn akẹkọọ mẹtadinlọgbọn, wọn ti sọ pe iranlọwọ t'awọn n ri gba lati ọdọ gomina ipinlẹ naa, AbdulRahman AbdulRazaq lo n jẹ k'awọn maa tẹsiwaju ni gbogbo igba.

Awọn alakoso ile-ẹkọ naa sọ pe awọn owo iranwọ ati ohun iwuri ti ijọba Kwara n ṣe fun wọn lo n mu ki eto ati ilana wọn tẹsiwaju lai fa sẹyin.

Giwa ile-ẹkọ naa, Captain Yakubu Okatahi lo fidi ọrọ yii mulẹ nibi abẹwo ti gomina ṣe lọ sile-ẹkọ naa lọjọ Iṣẹgun tii ṣe Tusidee, ọsẹ yii.
 
O ni miliọnu marundinlọgọrin naira ti gomina fun wọn lati fi ra ẹnjiini ọkọ ofurufu miran, to fi mọ ẹgbẹrun mẹwaa lita jet-A1, ati atunṣe awọn ibi to yẹ ninu ọgba naa, pẹlu awọn nnkan miran jẹ eyi to mu iwuri nla ba wọn.

Nibẹ lo tun ti jẹ ko di mimọ pe awọn yoo nilo iranlọwọo owo miran lati fi ṣagbeyẹwo owo oṣu ti wọn n san f'awọn oṣiṣẹ ati awọn olukọọ, pẹu awọn ohun miran.
 
Alakoso eto igbaniwọle nile ẹkọ naa, Mohammed Jimada Jibril ninu ọrọ rẹ, gbe o'suba kare fun gomina yii pẹlu bo ṣe n dide iranwọ lawọn asiko to ba yẹ, to si ni lara awọn ohun to n mu itẹsiwaju ba ile-ẹkọ naa niyẹn.
 
Bakan naa lo tun gbe oriyin fun bo ṣe pada di gomina ipinlẹ naa lẹẹkeji, ati bo ṣe di alaga ẹgbẹ awọn gomina lorileede Naijiria.
 
Gomina AbduRazaq wa gba wọn lamọran lati yago fun awọn ohun to mu ifasẹyin ba ile ẹkọ naa tẹlẹ, bii ikowojẹ, ati aṣilo owo.
 
Bakan naa ni gomina wọ aṣọ iyi f'awọn akẹkọọ to ṣẹṣẹ kẹkọọ-jade.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI