Dapọ Abiọdun lo sọ pe ki n dariji Amosun - Olu Itori - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, June 5, 2023

Dapọ Abiọdun lo sọ pe ki n dariji Amosun - Olu Itori


Kabiyesi, Olu tiluu Itori, Ọba Abdulfatai Akorede Akamọ ti jẹ ko di mimọ pe Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun lo gba oun lamọran lati foriji Sẹnetọ Ibikunle Amosun, iyẹn gomina ana n'ipinlẹ naa.

Ọba Akamọ lo sọrọ naa lọsẹ to kọja yii, ni papa iṣere MKO Abiọla to wa ladugbo Kutọ niluu Abẹokuta, iyẹn lakoko ti wọn n bura fun Ọmọọba Dapọ Abiọdun gẹgẹ bii gomina fun saa keji.

Nigba to n b'awọn akọroyin sọrọ nibi eto naa, Ọba Akamọ sọ pe lakoko idibo to gbe Dapọ Abiọdun wọle ni saa akọkọ loun jẹ ko yẹ awọn eeyan wi pe oun ko fẹ Amosun mọ, bẹẹ loun ko tun tẹle ninu eto idibo to kọja.

O ni ita gbangba loun ti sọ fawọn eeyan oun ni ijọba ibile Ewekoro wi pe oun ko fẹ Amosun, ṣugbọn to sọ pe Gomina Abiọdun lo ranṣẹ pe oun lati ba oun sọrọ, wi pe koun gbagbe awọn nnkan to ti kọja lọ.
 
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe; "Ki la tun n fẹ, bi ko ṣe ka dupẹ lọwọ Ọlọrun. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun fun igbe aye Gomina Dapọ Abiọdun, paapaa bo tun ṣe ko gbogbo eeyan mọra ninu ijọba rẹ. Mo si tun fẹ dupẹ fun ibi ti a wa lonii.

"Awa naa ree, nigba ti a ba n sọ fun awọn eeyan wa wi pe ọna ree, wọn a ro pe ti ara wa la n sọ. Ọpọ nnkan lo ti ṣẹlẹ, ṣugbọn ka dupẹ fun Ọlọrun.

"Ọpọ adojukọ lo waye ni saa akọkọ rẹ, lara wọn ni ajakalẹ arun Korona, iwọde ifopinsi ọlọpaa SARS, iyẹn ENDSARS. Ipenija nla mẹta lo ba pade nigba to kọkọ de, ṣugbọn ju gbogbo rẹ lọ, o mu awọn ileri rẹ ṣẹ.

"Mo le fi gbogbo ẹnu sọ wi pe Gomina Abiọdun ti pa opopona ilu mi laro, opopona ọhun ti ja geere. Mo tun le fi gbogbo ẹnu sọ pe a ti ni ọpọlọpọ ile-igbee fawọn araalu. Bẹẹ ni mo tun le fi gbogbo ẹnu sọ pe inu idunnu l'awọn eeyan wa n'ipinlẹ Ogun.

"Ohunkohun ti yoo ba ṣẹlẹ si wa ni ọla, a ti maa rii lonii. Gbogbo wa la ri bo ṣe ba ipinlẹ Ogun, bẹẹ la tun ri ipo ti ipinlẹ yii wa lonii, dajudaju, Ọlọrun n mu wa lọ si ipele to ga julọ.

"Bi ọla ṣe maa ri, oni la ti maa mọ. Ti ẹ ba ri Ọmọọba Dapọ Abiọdun ti a n sọ yii, ko ni ọta, bẹẹ ni ko ni ọrẹ, nitori pe ni ọdọ mi l'Ewekoro, mo pinnu, mo si jẹ k'awọn eeyan mọ pe mi o fẹ Amosun.

"Gomina si pe mi, o ni ki n jẹ ka rira, mo si lọ ba a. O sọ fun mi nigba naa wi pe ki n ma jẹ wuwa bii ti wọn. Papa iṣere yii la wa lọjọ naa, nibi ti wọn ti ju okuta fun un, ẹ wa wo nnkan to n ṣẹlẹ nibi lonii, ṣugbọn ọpẹ ni fun Ọlọrun, ẹnu ọpẹ wa ko si nii kan.

"Iṣẹlẹ naa ni Ọlọrun fi han wa pe ko si ẹni to to Oun, ki ẹnikẹni ma si fi ara rẹ we Ọlọrun. Ẹ jẹ ka wuwa bi eeyan, ka ma ṣe wuwa ni Ọlọrun. Ẹ jẹ ka ran awọn eeyan lọwọ, ka si jẹ ka fi àpẹẹrẹ rere lelẹ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI