Ileeṣẹ Gaasi lawọn eleyii lọ digun ja ki ọwọ ẹṣọ aabo too tẹ wọn l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 8, 2023

Ileeṣẹ Gaasi lawọn eleyii lọ digun ja ki ọwọ ẹṣọ aabo too tẹ wọn l'Ogun


Ileeṣẹ eleto aabo ijọba ipinlẹ Ogun ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ awọn meji kan ti wọn ko niṣẹ meji to kọja idigunjale lọ, ati pe asiko ti wọn lọ digun ja ileeṣẹ gaasi kan lọwọ palaba wọn segi.
 
Gẹgẹ bi agbẹnusọ ileeṣẹ aabo naa ti a mọ si Ogun State Community Social Orientation and Safety Corps, iyẹn So-Safe Corps, Ọgbẹni Mọruf Yusuf ṣe ṣalaye, o ni opin ọsẹ to kọja lọwọ tẹ wọn.Yusuf ni nnkan bi aago mọkanla aarọ, ọjọ Abamẹta tii ṣe Satide ni awọn adigunjale yawọ ileeṣẹ gaasi naa, iyẹn Green Fuel Company to wa ladugbo Estate, Onipanu, ijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta.

O sọ pe ibi ti wọn ti n ge awọn waya ina ati ọpa epo ileeṣẹ gaasi naa l'aṣiri wọn ti tu, ti ọwọ si tẹ wọn loju ẹsẹ ti wọno fẹẹ gbiyanju lati na papa bora.


Siwaju sii ni agbẹnusọ naa jẹ ko ye wa pe ọkada Bajaaji ti nọmba idanimọ rẹ jẹ TRE 461VL ati ọkada Honda ti nọmba tiẹ jẹ AAB 495VE ti wọn gbe lọ jale ọhun ni wọn gba lọwọ wọn nibẹ.
 
Bakan naa lo fi ye wa pe, ọga awọn, Olusọji Ganzallo ti paṣẹ pe ki wọn ko awọn mejeeji, pẹlu awọn ohun ti wọn gba lọwọ wọn lọ si teṣan ọlọpaa ẹkun Onipanu fun iwadii kikun.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI