Ile-ẹjọ paṣẹ ki wọn ti Daniel mọle, ọmọ ọdun mẹta lo gb'aṣọ iyi lara rẹ l'Ondo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 27, 2023

Ile-ẹjọ paṣẹ ki wọn ti Daniel mọle, ọmọ ọdun mẹta lo gb'aṣọ iyi lara rẹ l'Ondo


Ile-ẹjọ mọlẹbi kan to wa lagbegbe Oke-Ẹda niluu Akurẹ, ipinlẹ Ondo ti paṣẹ pe ki wọn lọ ti Daniel Udoh, ẹni ọdun mejilelọgbọn ti wọn lo fipa ja ibale ọmọ ọdun mẹta s'ọgba ẹwọn, titi ti ọjọ igbẹjọ miran yoo fi waye.
 
Udoh ti wọn lo n gbe lojule karun-un, adugbo Alayere to wa lopopona Ọda niluu Akurẹ la gbọ pe o fipa ba ọmọ naa tọjọ ori rẹ ko tii ju ọdun mẹta lọ laṣepọ karakara.
 
Nigba to n fẹsun kan Daniel  niwaju Onidajọ FọlaṢhade Aduroja, Agbefọba Martins Olowofẹsọ, sọ pe nnkan bi aago marun-un, ọjọ kejila, oṣu kẹfa, ọdun ti a wa yii ni Daniel ṣiṣẹ buruku naa.
 
O ni niṣẹ lo f'ọgbọn tan ọmọ naa lọ sinu yara rẹ, nibi to ti gba aṣọ iyi ọmọ naa lai foju aanu wo o.
 
Siwaju sii lo sọ pe ariwo igbe ọmọ naa lo ta si mama rẹ leti, to fi sare lọ lati wo ohun to n ṣẹlẹ si ọmọ rẹ. Iyalẹnu nla lo jẹ nigba to ri Daniel lori ọmọ rẹ, to si n laagun bi ẹni to wa nibi ina burẹẹdi, eyi lo jẹ ko pariwo sita faraye.

Awọn ara adugbo lo sọ pe wọn pada lọ fa Daniel le awọn ọlọpaa lọwọ, ko to di pe wọn foju rẹ ba ile-ẹjọ.
 
Agbefọba ọhun sọ pe ẹsun ti wọn fi kan Daniel yii lo tako iwe ofin lilo ọmọde nilokulo ati titapa si ẹtọ awọn ọmọde ti abala kejilelọgbọn, tọdun 2006 nipinlẹ Ondo.
 
O wa rọ ile-ẹjọ lati ṣi fi Daniel pamọ sọgba ẹwọn titi amọran labẹ ofin lati ọdọ ajọ Directorate of Public Prosecution’s, DPP yoo fi jadee.
 
Bo tilẹ jẹ pe Daniel sọ pe oun ko jẹbi pẹlu alaye, ṣugbọn ti Onidajọ  Aduroja sọ pe ko ṣi fi alaye rẹ silẹ naa, fun idi eyi, o ni ki wọn ṣi lọ fi ọkunrin naa pamọ sọgba ẹwọn Olokuta titi digba ti wọn yoo tun pe ẹjọ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI