Ileya: Ẹ gbadura fun Naijiria - AbdulRazaq gba awọn to lọ gun Arafa lamọran - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, June 28, 2023

Ileya: Ẹ gbadura fun Naijiria - AbdulRazaq gba awọn to lọ gun Arafa lamọran


Bi awọn Musulumi kaakiri agbaye ṣe n ṣayẹyẹ ọdun Ileya lonii, Ọjọru, Wẹsidee, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ba gbogbo awọn ẹlẹsin naa yọ, to si gba wọn lamọran lati maa gbadura fun Naijiria.

Kii ṣe awọn Musulumi to wa ni Naijiria lọwọlọwọ nikan ni Gomina AbdulRazaq gba lamọran lati gbadura fun Naijiria, bi ko ṣe awọn to lọ gun oke Arafa ni Saudi Arabia.

Bakan ni gomina tun gba wọn lamọran lati maa lo asiko yii fi ifẹ han si gbogbo eeyan, ki Naijiria le wa ni iṣọkan.

O ni asiko yii jẹ apẹẹrẹ igbagbọ, ati ifarajin fun Ọlọrun.

Gomina AbdulRazaq sọ pe lara awọn aṣeyọri lati jẹ Musulumi ni gigun oke Arafa ati gbigbadura si Ọba to da aye ati ọrun, ati pe ki wọn lo anfaani rẹ lati fi Naijiria si ikawọ Ọlọrun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI