Bọwale Mumin, Ilọrin
Lojuna lati jẹ ki iṣẹ agbẹ ati ọgbin tubọ kẹsẹ jare, eyi ti yoo mu idagbasoke ba eto ọrọ aje, ijọba ipinlẹ Kwara ti tọwọ bọwe adehun pẹlu ijọba ilẹ Faranse.
Minisita fọrọ eto idagbasoke ipinlẹ lorileede France, Dr. Chrysoula Zacharopoulou lakoko to n ṣabẹwo s'ipinlẹ Kwara ṣe ileri wi pe ijọba ilẹ naa yoo fọwọsowọpọ lati rii pe idagbasoke waye lori eto agbẹ nipinlẹ Kwara.
Iwe adehun nla meji ọtọọtọ la gbọ pe Ọmọwe Chrysoula tọwọ bọ, ninu eyi to nii ṣe pẹlu ọrọ agbẹ ati ogbin, to fi mọ fifi ẹran jẹko ati ohun ọsin.
No comments:
Post a Comment