Iya arugbo jabọ sinu kọnga, nibi to ti n pọn omi lẹsẹ rẹ ti yọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 20, 2023

Iya arugbo jabọ sinu kọnga, nibi to ti n pọn omi lẹsẹ rẹ ti yọ


Iṣẹlẹ manigbagbe miran lo tun ṣẹlẹ nipinlẹ Kwara l'ọjọ Aje, Mọnde ana, nigba ti wọn sọ pe iya agbalagba, ẹni ọdun mẹtadinlọgọta kan, Jamiu Sikirat jabọ sinu kọnga, to si gbabẹ sọda sọrun alakeji.
 
Agboole Ile-Agunko to wa lagbegbe Adẹta, ilu Ilọrin, ijọba ibilẹ Ilọrin West la gbọ pe iṣẹlẹ ọhun ti waye nirọlẹ ọjọ Aje, tii ṣe Mọnde, ọsẹ yii.
 
Nnkan bi aago meje alẹ ku iṣẹju mejidinlogun ni wọn sọ pe ijamba yii waye, to si ṣe ọpọ ni kayeefi, nitori bi wọn ṣe sọ pe kii ṣe igba akọkọ ree ti iya naa yoo maa pọn omi ninu kọnga ọhun.
 
Agbẹnusọ ileeṣẹ pannapanna nipinlẹ naa, Hassan Hakeem Adekunle, nigba to n f'idi iṣẹlẹ ọhun mulẹ ṣalaye pe ọkan lara awọn ara adugbo naa ti orukọ rẹ n jẹ Muhammad Jamiu, lo ranṣẹ pe awọn lori foonu.
 
O lawọn ko fi ọrọ ọhun falẹ, to mu k'awọn tete gbera lọ sibẹ lati doola ẹmi iya naa, ṣugbọn to sọ pe ẹpa ko boro mọ nigba t'awọn yoo fi debẹ.
 
Adekunle tẹsiwaju pe awọn ṣaa gbiyanju gidi lati rii pe awọn gbe oku iya agba naa jade, ti wọn si ti fa a le ọkan lara awọn mọlẹbi rẹ, Alfa Abdulganiyu Akuko lọwọ.
 
Koda, o fi kun un pe iwaju awọn ọlọpaa ẹkun Adewọle tiluu Ilọrin lawọn ṣe fa oku naa le mọlẹbi lọwọ.
 
O loun t'awọn eeyan sọ fun wọn ni pe iya naa lọ pọn omi ninu kọnga yii ni, ati pe ibi to ti n pọn omi lọwọ ni ẹsẹ rẹ ti yọ, to si mu ori wọnu kọnga yii.
 
Bẹẹ lo ọga awọn, Ọmọọba Falade John Olumuyiwa, naa ti kọminu lori iṣẹlẹ ọhun, to si gba awọn eeyan lamọran lati ṣọra nipa riran ọmọde lọ sidii kọnga, ati pe ki awọn eeyan gbiyanju lati maa daabo bo kọnga wọn, ki wọn si yago f'awọn ohun to le ṣe akọba nidi ẹ.
 
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI