Wọn ju iyaale ile sẹwọn ọdun kan ataabọ, ọkọ rẹ lo lu ni jibiti miliọnu meji naira - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 20, 2023

Wọn ju iyaale ile sẹwọn ọdun kan ataabọ, ọkọ rẹ lo lu ni jibiti miliọnu meji naira


Ile-ẹjọ Majisireeti to wa niluu Kano ti ju iyaale ile kan, Elizabeth Gift sẹwọn kan ataabo gbako lori ẹsun wi pe o lu ọkọ rẹ ni jibiti owo to le diẹ ni miliọnu meji N2,050,000 naira.
 
Gẹgẹ bi agbefọba, Amofin Jamilu Abubakar to f'oju Elizabeth ba ile-ẹjọ, o ni ninu oṣu kẹrin, ọdun yii ni ọkọ obinrin naa, iyẹn Ọgbẹni Benefice fi owo ọhun ran an niṣẹ.
 
Banki ni Benefice sọ fun iyawo rẹ, Elizabeth pe ko gbe owo naa lọ, ṣugbọn to pada sile wi pe awọn kan ti fi ohun ija oloro gba owo naa lọwọ oun, ati pe wọn ti salọ.
 
Ninu iwadii ti ọkunrin naa ṣe, lo ti mọ pe irọ ni iyawo oun n pa, ati pe ko sẹni to gba owo naa lọwọ ẹ, idi ree to fi gba teṣan ọlọpaa lọ lati fi to wọn leti, ti wọn si gbe obinrin naa.

Abubakar ṣalaye pe iwadii lo pada fidi rẹ mulẹ wi pe Elizabethlo lọ lẹdi apo papọ pẹlu awọn kan lati gba owo naa dani, ati pe awọn yoo tun ṣi fi ọgbọn arekereke pa owo sii.

Nibẹ ni Elizabeth ti gba pe oun jẹbi ẹsun ole ati jibiti ti wọn kan oun.

Loju ẹsẹ ni Onidajọ Halima Nasir ti sọ pe ki Elizabeth lo fi ẹwọn oṣu kejidinlogun gbara, ati pe o gbọdọ wa ọna bi yoo ti da gbogbo owo to gba lọwọ ọkọ rẹ naa pada lai ki ẹyọkan
 
Bakan naa ni ile-ẹjọ tun sọ pe anfaani wa fun Elizabeth lati san owo itanran, ẹgbẹrun lọna aadọta naira, iyẹn bi ko ba fẹẹ lọ sẹwọn oṣu mejidinlogun naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI