Boroboro l'awọn mẹrin ti ẹ n wo yii n ka, nigba tọwọ palaba wọn segi lori ẹsun wi pe wọn ko niṣẹ meji ju ki wọn maa ji Ewurẹ elewurẹ gbe lọ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Gombe lo f'idi rẹ mulẹ pe ọwọ awọn ti tẹ ọrẹ mẹrin kan, Hassan Adamu, ẹni ọdun mejidinlogun; Abdulaziz Abubakar, ẹni ogun ọdun; Abdullahi Shuaibu, ẹni ọdun marundinlọgbọn, ati ẹnikan ti wọn ko darukọ rẹ lori ẹsun ole jija.
Agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ naa, ASP Mahid Abubakar, nigba to n ṣalaye, o ni Kẹkẹ Maruwa lawọn mẹrẹẹrin fi n ji Ewurẹ gbe lawọn adugbo bii Malam Inna ati Wuro Kesa.
Abubakar ni bi wọn ba ti ji ewurẹ gbe tan, niṣe ni wọn yoo lọ ta a danu ki aṣiri wọn ma ba a tu, ati pe Kẹkẹ Maruwa ni wọn n lo lati fi ṣiṣẹ buruku ọhun.
O ni awọn mẹrẹẹrin ti jẹwọ pe otitọ ni, ati pe iṣẹ eṣu, to si ni wọn ti n ṣeleri wi pe awọn ko tun ni jẹ ṣe bẹẹ mọ, ṣugbọn o sọ pe iwadii tun ṣi n lọ lọwọ lori wọn.
Bakan lo ni ileeṣẹ ọlọpaa yoo foju wọn ba ile-ẹjọ lẹyin ti iwadii ba tubọ pari, nitori pe awọn ti gba ọkan lara awọn ewurẹ ti wọn jigbe ati Kẹkẹ Maruwa ti wọn n lo fi jale lọwọ wọn.
No comments:
Post a Comment