Nitori ẹsun jibiti! Wọn ju ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin l'Abuja tẹlẹri sẹwọn ọdun marun-un - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 18, 2023

Nitori ẹsun jibiti! Wọn ju ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin l'Abuja tẹlẹri sẹwọn ọdun marun-un


Lọjọ Ẹti tii ṣe Furaidee to kọja yii ni ajọ to n gbogun iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede Naijiria, EFCC ṣe aṣeyọri nipa idajọ ododo, lori ọkan lara awọn ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin tẹlẹri, Ọnarebu Mansur Ali Mashi, ti wọn gbe lọ siwaju ile-ẹjọ lori ẹsun jibiti, ti ile-ẹjọ naa si pada juu sẹwọn ọdun marun-un pẹlu iṣẹ aṣekara.
 
Ọnarebu Mansur, ẹni to ti figba kan ri ṣoju ẹkun Mashi Dutsi nile igbimọ aṣoju-ṣofin l'Abuja ni ajọ Economic and Financial Crimes Commission, EFCC fẹsun jibiti miliọnu mejila-le-nigba N212m naira kan.

Yatọ si Mansur Ali Mashi, ti wọn fẹsun mẹjọ ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu jibiti kan, a gbọ pe ajọ EFCC tun fẹsun jibiti yii kan awọn oṣiṣẹ banki mẹta ti wọn lawọn naa mọ nipa bi owo ọhun ṣe poora.
 
Awọn mẹta naa ni Abdulmumini Mustapha, Shehu Aliyu ati Muazu. Ọdun mejila gbako la gbọ pe wọn ti wa lori ẹjọ naa, ko to di pe idajọ pada waye lọjọ Ẹti to kọja yii.

Ajọ EFCC sọ pe ileeṣẹ kan ni ọkunrin naa fi ya owo ọhun lọwọ banki ti awọ mẹta naa ti n ṣiṣẹ, to si jẹ pe niṣe ni wọn pin owo naa mọ ara wọn lọwọ. 
 
Nigba ti igbẹjọ naa waye l'Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee to kọja, a gbọ pe Mansur Ali Mashi ko yọju si kọọtu, eyi to mu ki ile ẹjọ sọ pe o jẹbi ẹsun mẹjọ ti ajọ EFCC fi kan, bẹẹ naa ni Muazu toun naa ko yọju, ile ẹjọ pe oun naa jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.
 
Ile-ẹjọ naa ti wa paṣẹ pe ki wọn lọ gbe awọn mejeeji yii wa siwaju ohun, lati le da ẹjọ naa niwaju wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI