Ko si igbeyawo kankan laarin emi ati Damọla Ọlatunji - Arugba pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 1, 2023

Ko si igbeyawo kankan laarin emi ati Damọla Ọlatunji - Arugba pariwo sita


Gbajugbaja oṣerebinrin nni, Bukọla Awoyẹmi ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Bukọla Arugba ti pariwo sita wi pe ko si igbeyawo kankan laaarin oun ati Damọla Ọlatunji, gbajugba oṣere tiata.
 
Bukọla Arugba lo sọrọ naa loju opo ayelujara rẹ laipẹ yii, to si ni baba awọn ọmọ oun lasan lo jẹ.
 
Ninu ohun ti Arugba gbe sita, iyẹn iwe ti agbẹjọro rẹ kọ, lo ti sọ pe ajọṣepọ to wa laaarin oun ati Damọla Ọlatunji ti d'opin, ko si s'ohun to le pa wọn pọ mọ, bi ko ṣe ọrọ awọn ọmọ wọn.

O sọ sinu lẹta naa wi pe

“Awa ti a jẹ agbẹnusọ fun Arabinrin Bukọla Awoyẹmi, ti awọn eeyan tun mọ si Arugba, nipaṣe aṣẹ ti a gba lati ọwọ rẹ.

“Ẹ dakun, ẹ mọ daju pe onibara wa, Bukọla Awoyẹmi ati Damọla Ọlatunji ko si papọ mọ. Onikaluku ti lọ lọtọọtọ, ati pe eyi si wa latari wi pe ko si ifẹ kankan laaarin wọn mọ. Wọn ko f'igba kankan fẹ ara wọn, ṣugbọn Ọlọrun fi ọmọ meji ta wọn lọrẹ (ibeji).

“Awọn mejeeji ti panupọ lati rii pe ọrọ alaafia awọn ọmọ wọn jẹ wọn logun, lai si ohunkohun ti yoo ṣe wọn.

“Onibara wa wa gbadura fun Ọgbẹni Damọla Ọlatunji.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI