Mejilelaadọta l'awọn ọmọ 'Yahoo-Yahoo' tọwọ tẹ n'ipinlẹ Ogun laaarin ọsẹ kan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 10, 2023

Mejilelaadọta l'awọn ọmọ 'Yahoo-Yahoo' tọwọ tẹ n'ipinlẹ Ogun laaarin ọsẹ kan


Adeolu Gbọlaruwa, Abẹokuta
 
Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, lorileede yii, ẹka tipinlẹ Ekoo ti sọ pe awọn gendekunrin mejilelaadọta ti wọn ko niṣẹ meji ju jibiti ori ayelujara ti a mọ si Yahoo-Yahoo lọ.
 
Wọn ni ipinlẹ Ogun lọwọ ti tẹ gbogbo wọn ni agbegbe ọtọọtọ laaarin ọsẹ ti a wa yii.
 
Lara awọon tọwọ tẹ ni; Ọlamilekan Jamiu Ayuba, Ogundeyi Oluwaṣeun Kayode, Abdulrahman Ismail Abiodun, Blessing Oluwaseun Omokaro, Olasupo Ademola Ridwan, Adetola Roqeeb Salau, Adeola Alamin Ideraoluwa, Victor Daniel Osikwemeh, Taiwo Ayobami, Eleshin Ademola, Ayomipo Adelere, Shogbesan Quadri, Sanni Qudus, Olanite Oluwatosin, Olatunbosun Yusuf Alameen, Aderemi Adewole Adekunle, Olawunmi Oluwaseyi Tosin, Ayobado Joseph Olatunde, Ariyo Temitope Taofik, Olugbade David, Olumayowa Adeyemi Adedayo, Aremu Ahmed Alabi, Akintosoye Tomiwa Pelumi, Fatoye Damilare Akanbi ati Adio Emmanuel Oyebanji.
 
Awọn yooku ni; Adekoya Samuel, Adebayo Taiwo, Olawale Bayole, Emmanuel Benjamin, Omotosho Ayobami, Usman Boluwatife, Adewale Adeniyi, Obadina Olawunmi, Ashiru Abdullahi, Ahmed Mubarak, Idowu Kazeem, Olukoya Emmanuel,Yusuf Lukman, Agesin Eniola, Tajudeen Mustapha, Falola Olalekan, Usman Funsh, Bolaji Usman, Ayiyon Naoh, Mohammed Adeoye, Babatunde Seun, Afela Mustapha, Yusuf Habeeb Olanrewaju, Alao Ayomide, Oyeleye Uman Abduljelil Raji, Adeniyi Abdulmojeeb.
 
Gẹgẹ bi EFCC ṣe sọ, wọn ni ọjọ meji pere, iyẹn Ọjọru tii ṣe Wẹsidee ati Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, ọjọ keje ati ọjọ kẹjọ, oṣu ti a wa yii lọwọ tẹ wọn, latari olobo to ta si wọn leti nipa wọn.
 
Lara awọn ohun ti wọn gba lọwọ wọn ni kọmputa alagbeka, foonu, mọto bọginni ati awọn ẹrun miran.
 
Bẹẹ ni wọn sọ pe wọn yoo foju ba ile-ẹjọ bi iwadii ba tubọ pari.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI