Origin Bitters ti wọn jigbe lo gbe ọrẹ mẹta de kootu l'Ekoo, wọn ti wa ni Kirikiri - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 10, 2023

Origin Bitters ti wọn jigbe lo gbe ọrẹ mẹta de kootu l'Ekoo, wọn ti wa ni Kirikiri


Ọlaide Ọṣinuga, Ekoo
 
Ile-ẹjọ Majisireeti to wa niluu Ikẹja, ipinlẹ Ekoo ti paṣẹ pe ki wọn ṣi lọ fi awọn mẹta kan, Abdullahi Alimi, ẹni ọdun mẹrinlelogoji; Ọladipupọ Fagbe, ẹni ọdun mẹtalelogoji ati Rasaq Alimi, toun jẹ ọmọ ọdun mọkanlelogun pamọ sọgba ẹwọn Kirikiri, titi digba ti igbẹjọ yoo tun waye lori wọn.
 
Ẹsun mẹrin ọtọọtọ ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekoo fi kan awọn mẹta naa niwaju Onidajọ A. Akinyẹmi, eyi to nii ṣe pẹlu idigunjale ati gbigba ẹru ole pamọ.
 
Bo tilẹ jẹ pe Onidajọ AKinyẹmi ti tare iwe ẹsun naa sọdọ ajọ  Director of Public Prosecutions, DPP, fun amọran, to si sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yii, sibẹ o ni ẹri to wa niwaju oun ko ṣee fọwọ bo.
 
Agbefọba to fẹsun kan wọn, iyẹn DSP Chinalu Nwadione, sọ pe ọjọ kẹtala, oṣu kẹrin, ọdun yii ni wọn lọ digun ja Musa Ganiyu lole lopopona Ọgba to wa ni Agege nipinlẹ Ekoo.
 
O ni ọbẹ ni wọn ko dani lọjọ, ti wọn si gba ẹgbẹrun lọna ogun naira lọwọ ẹ.
 
Bakan naa lo tun sọ pe awọn mẹta yii tun ji paali ọti Origin Bitter mẹrinlelẹẹdẹgbẹta (504), ẹyi ti owo rẹ ko din ni miliọnu mẹrin aabọ naira.
 
Ileeṣẹ Fafem Haulage Nigeria Ltd la gbọ pe o ni awọn ọti naa, gẹgẹ bi Nwadione ṣe sọ.
 
Bẹẹ lo tun sọ pe wọn tun ji katọọnu ọti Origin Bitters yii marun-un, eyi ti owo rẹ jẹ ẹgbẹrun marundinlaadọta naira.
 
O fi kun ọrọ rẹ wi pe awọn ẹsun yii lo tako iwe ofin ọdaran ipinlẹ Ekoo ti ọdun 2015 ni abala 411, 297, 287 ati 329.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI