Mọkandinlaadọta lọmọ Yahoo tọwọ tẹ l'Ekiti ati Ọyọ - EFCC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, June 30, 2023

Mọkandinlaadọta lọmọ Yahoo tọwọ tẹ l'Ekiti ati Ọyọ - EFCC


Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ gendekunrin mọkandinlaadọta lori ẹsun jibiti ori ayelujara ti a mọ si 'Yahoo-Yahoo'.

Ipinlẹ Ekiti ati Ọyọ ni ajọ EFCC ṣalaye pe ọwọ awọn ti tẹ awọn eeyan naa l'opin ọsẹ to kọja yii.
 
Ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹfa, ọdun 2023 ni ajọ EFCC sọ pe ọwọ ti kọkọ tẹ awọn mẹtadinlaadọta lagbebe Ikẹrẹ ati Iworoko to wa niluu Ado-Ekiti, ipinlẹ Ekiti, lẹyin iṣẹ finni-finni ti wọn ṣe.
 
Lara awọn tọwọ tẹ naa ni Adeyẹmi Joshua Adeniran, Ajaye Redmond Damilare, Nwaji Mathew, Jẹgẹdẹ Boluwaji Victor, Oyetunji Sunday Wọle, Damilọla Awopetu Ayọmide, Ajayi Temitọpẹ Ayọmide, Babajide Adebisi Victor, Balogun Precious Akinwale, Obie Jacob Onatakaroma, Olonitọla Ọlamilekan, Ajewọle Ojo Kayọde, Aina Toluwani Emmanuel, Adebayọ Akinwumi Oluwadamilare, Ọmọwaye Oluwatosin Ọlamilekan, Oyewale Francis Ọyọmilekan, Arowolo Ayọmide Gift, Ṣhotọnwa Babatunde Ọmọtoyọsi, Ochochie Silas Ochola, Ojo Ṣeyitan David, Onile Ayọdeji Raphael ati Abiọdun Oluwatosin Ọpẹyẹmi.

Awọn miran ni: Adebayọ Gbenga Musbau, Oyebade Ayọmide Ọlamide, Egunjọbi Samuel Gbenga, Ọladokun Tọheeb Adekọla, Adeṣọla Bẹnjamin Adebọwale, Ẹdamisan Ọlakunle, Adeṣọla Isaac Babatunde, Oyewọle Gideon David, Lawal Tosimile Moses, Adeleke Adekunle Samson, Ọladiti Abiọdun Akanji, Ajayi Charles Temitayọ, Adeyẹmi Oluwaṣẹgun Adeboye, Ernest Solomon Temitọpẹ ati Atoun Ọlalekan Timilẹhin.

Awọn yooku ni: Ọlọrunyọmi Ṣina Ayọ, Babatunde Emmanuel Babalọla, Yusuf Saka Ọlaoluwatobi, Falaye Babatunde Temitọpẹ, Ilesanmi Damilọla Ayọmide, Badmus Yusuf Ọmọbọlaji, Kọmọlafẹ Emmanuel Fẹranmi, Babajide Adebisi Victor, Adamọlekun Ọlamiji ati Oṣhatimi Samuel Ọmọniyi.

Siwaju sii ni ajọ EFCC tun jẹ ko di mimọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ fa afurasi ọmọ 'Yahoo' meji, ẸMiọla Usman ati Kamọrudeen Quayum le awọn lọwọ.

Wọn jẹ ko ye wa pe mọto bọginni mẹẹdogun, kọmputa alagbeka mẹrindinlogun ati foonu olowo nla mẹtadinlọgọrin, to fi mọ awọnn ẹru ofin miran ni wọn gba lọwọ wọn ni kete tọwọ palaba wọn segi
 
EFCC wa fi kun ọrọ rẹ wi pe awọn yoo foju wọn ba ile-ẹjọ lẹyin iwadii.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI