Ayọmide, Adeleke ati Ṣhagari ṣalaye bi wọn ṣe pa ọga ologun ori omi l'Ondo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 1, 2023

Ayọmide, Adeleke ati Ṣhagari ṣalaye bi wọn ṣe pa ọga ologun ori omi l'Ondo


Boroboro l'awọn ọrẹ mẹta kan tọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ondo tẹ laipẹ yii lori iku oṣiṣẹ ologun ori omi ti a mọ si Naval Officer, Sub. Lt. Samuel Akingbohun n ka bi ẹyẹ orofo, ti wọn si ṣalaye lẹkunrẹrẹ nipa bi wọn ṣe pa ọkunrin naa.
 
Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii l'awọn mẹtẹẹta naa tọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹtadinlogun si ogun ọdun lọ, Ayọmide Sambo, ọmọ ogun ọdun; Johnson Adeleke, ọmọ ogun ọdun ati Francis Ṣhagari toun jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogun jẹwọ ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa. 
 
Ilu ti wọn n pe ni Idoani to wa nijọba ibilẹ Oṣe, ipinlẹ Ondo la gbọ pe wọn ti pa Akingbohun laipẹ yii, ko to di pe wọn na papa bora. A gbọ pe irin nla kan ni wọn fọ mọ-ọn lori ati woropọn lasiko ti ọrọ ṣebi ọrọ laarin wọn.
 
Ayọmide nigba to n sọrọ, sọ pe oloogbe naa gba Adeleke leti, o si tun sẹẹ nigbo lọjọ naa, eyi to bi oun ati Ṣhagari ninu, ti wọn fi lọ dena de e, ti wọn si koju ija sii.
 
O ni b'awọn ṣe pa Akingbohun tan, l'awọn gbiyanju lati na papa bora, ṣugbọn ti ọwọ awọn ara agbegbe naa pada tẹ awọn loju ẹsẹ.
 
Ayọmide ni, “A pada oṣiṣẹ ologun ori omi naa loju ọna nigba ti a n lọ ni. Ọna naa kere gidi, ko gba wa, eyi lo jẹ ki ọkan lara wa fara gba a, nitori pe ọna ọhun ko dara.
 
“Ọkunrin naa sẹ eeyan wa yii nigbo lori, o si tun fi ibinu gba a leti. Loju ẹsẹ la ti bẹrẹ sii bẹbẹ ko to di pe onikaluku lọ. Ọrẹ wa yii lo wa sọ fun wa pe ayederu oṣiṣẹ ni ọkunrin naa lẹyin to ti lọ tan.
 
“Nibẹ la ti gbe ọkada lati tẹle lẹyin ti a si lo dẹbuu rẹ, ka too koju ẹ. Ọrẹ wa ati ọkunrin yii bẹrẹ sii sọrọ si ara wọn, ko to di pe mo lọ gbe irin, mo bẹrẹ sii fi luu.”
 
Adeleke nigba toun naa sọrọ jẹ ko di mimọ pe oun ko lọwọ si bi wọn ṣe lu ọkunrin naa, to si loun ko pẹlu ba wọn lu.
 
“Mo fẹẹ lọ yọ 'Power Bank' mi lọjọ naa ni, mo wa ṣeeṣi fi ejika gun un lẹgbẹ. O fọ mi leti, o si tun sẹ mi nigbo lori. Nigba naa, a ko mọ pe oṣiṣṣe ologun ori omi ni.
 
“Mo ti fẹ maa salọ kuro Idoani ko to di pe ẹgbọn mama mi pe mi wi pe ki n maa bọ ni agọ ọlọpaa. Ibẹ ni mo ti lọ ba wọn.”
 
Ṣhagari Francis, ninu ọrọ tiẹ sọ pe, “Mi o si lara awọn to luu, emi kan tẹle wọn lasan ni. Mama mi lo mu mi lọ teṣan lati beere boya mo lọwọ si bi wọn ṣe pa ọkunrin naa.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI