O tun ṣẹlẹ o! Wọn ti ji Imaamu agba l'Ondo gbe - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 18, 2023

O tun ṣẹlẹ o! Wọn ti ji Imaamu agba l'Ondo gbe


Iroyin to tẹ wa lọwọ laipẹ yii ti fidi rẹ mulẹ pe awọn agbebọn kan ti ji Imaamu agba agbegbe Uso, ijọba ibilẹ Ọwọ, ipinlẹ Ondo, Alaaji Ibrahim Oyinlade gbe salọ, ti ko si tii sẹni to le sọ ibi ti wọn gbe e lọ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, alẹ ana tii ṣe Abamẹta, Satide ni wọ ji Alaaji Oyinlade salọ, lakoko ti wọn lo n ṣiṣẹ lọwọ ninu oko to da, eyi to wa lagbegbe Asolo Camp.

Lara awọn mọlẹbi Imaamu agba naa sọ pe awọn to ji eeyan wọn gbe pe lori fooonu, ṣugbọn wọn ko tii sọrọ lori boya wọn yoo san owo tabi bẹẹ kọ.

Ẹni naa sọ pe awọn ajinigbe ọhun fidi rẹ mulẹ pe Alaaji Oyinlade wa lahamọ awọn, bo tilẹ jẹ wọn ko tii beere owo lọwọ awọn.

O lawọn ti fi to ileeṣẹ ọlọpaa ẹkun Uso leti, koda awọn tun ti lọ fi to ileeṣẹ fijilante naa leti, lati bawọn gbe igbesẹ ti wọn yoo fi ri baba naa gba jade lai farapa.

DSP Funmilayọ Ọdunlami, to jẹ agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa fidi rẹ mulẹ, to si lawọn ti bẹrẹ iwadii lẹkunrẹrẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI