Ọlọkada fipa ja ibale ọmọ ọdun mejila l'Ondo, lo ba na papa bora - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 3, 2023

Ọlọkada fipa ja ibale ọmọ ọdun mejila l'Ondo, lo ba na papa bora


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti sọ pe iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹu lati rọwọ to afurasi ọdaran ọlọkada kan to fipa ja ibale ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mejila kan niluu Igbọkọda, to wa n'ijọba ibilẹ Ilajẹ, ipinlẹ naa.
 
Ọmọ ọdun mejila naa ti a fi orukọ bo laṣiri ni iroyin fi to wa leti pe ọlọkada naa ti ẹnikẹni ko tii mọ orukọ rẹ titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii tan ni wọn lo fipa ba ọmọdebinrin naa laṣepọ ninu ile akọku kan, to si gbabẹ na papa bora.
 
Wọn ni pọfu-pọọfu ni ọmọ naa n ta lasiko ti ọlọkada ọhun, ẹni ti wọon lọmọ bibi ipinlẹ Kebbi ni, da a duro bi ẹni to fẹẹ ra ọja lori ẹ.
 
Bo ṣe daa duro, ni wọn lo tan ọmọ naa lọ sinu ile akọku kan to wa nitosi, nibẹ lo si ti raaye fipa ba a laṣepọ. Nibẹ ni wọn ti sọ pe gbogbo bi ọmọ naa ṣe maa pariwo, niṣe lo fi aṣọ dii lẹnu. Igba to ṣetan ni wọn lo gbe ọkada rẹ, to si juba ehoro.

Ile ni ọmọ naa gba lọ, lọdọ mama rẹ, to si lọ ṣalaye ohun ti oju rẹ ri. Iya rẹ ti wọn pe ni Joy ko fọrọ ọhun falẹ rara to fi gba teṣan ọlọpaa lọ lati fi to wọn leti.
 
Joy lo ṣalaye fawọn ọlọpaa wi pe nnkan bi aago meje irọlẹ, ọjọ kọkandinlogun, oṣu karun-un, ọdun yii niṣẹlẹ ọhun waye. Bẹẹ lo sọ pe nibi tọmọ naa ti n ṣalaye foun lo ti daku, ṣugbọn to pada ji l'ọsibitu ti wọn gbe e lọ.
 
Olufumilayo Odunlami-Omisanya, to jẹ agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa nigba to n sọrọ jẹ ko di mimọ pe awọn ti bẹrẹ, koda, o ni awọn ti tọpinpin afurasi naa de ipinlẹ Kebbi, to si loun nigbagbọ pe ọwọ yoo tẹ ẹ laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI