AbdulRazaq ba Tinubu yọ lori bo ṣe di alaga ECOWAS - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, July 11, 2023

AbdulRazaq ba Tinubu yọ lori bo ṣe di alaga ECOWAS


Gomina ipinlẹ Kwara ati alaga ẹgbẹ awọn gomina lorileede Naijiria AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pe ipo to tọ si Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu ni wọn gbe lee lọwọ gẹgẹ bi alaga ajọ ECOWAS, iyẹn Economic Community of West African States.
 
AbdulRazaq ni igbagbọ ati idaniloju ti awọn akẹgbẹ Tinubu nilẹ Adulawọ ni ninu ẹ, lo fa a ti wọn fi yan an gẹgẹ bi alaga wọn.
 
Bẹẹ lo ni k'awọn eeyan kaakiri agbaye gbauruku tii, fun idagbasoke ilẹ Adulawọ lapapọ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI