AbdulRazaq ni k'awọn araalu gbaruku ti Tinuibu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, July 2, 2023

AbdulRazaq ni k'awọn araalu gbaruku ti Tinuibu


Gomina AbdulRahman Abdulrazaq ti gba awọn ọmọ Naijiria, paapaa awọn ọmọ ipinlẹ Kwara lamọran lati gbaruku iṣakoso Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu, to si fọkan wọn balẹ wi pe gbogbo ohun to lọ soke ṣi n pada bọ nilẹ laipẹ jọjọ.
 
Nibi ayẹyẹ ọdun Bareke to waye niluu Ilọrin, lọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ yii ni Gomina AbdulRazaq ti sọrọ naa jade, to si ni fun idagbosoke ni gbogbo ohun to n ṣe lakoko yii.

Ọdun Bareke naa ni gomina ti gba Ẹmir tiluu Ilọrin, Ọmọwe Ibrahim Sulu-Gambari lalejo, to si gbe oṣuba kare fun ori ade naa lori ipa to n ko lẹka eto aabo, iṣọkan, idagbasoke ati ifẹ kaakiri ipinlẹ naa.

Siwaju sii ni AbdulRazaq sọ pe bi ẹni pe obinrin wa ninu oyun, to si n reti ọmọ rere ni iṣakoso Tinubu ri, nitori pe ilọsiwaju ati idagbasoke rere ni yoo bi nigbẹyin, eyi ti gbogbo araalu yoo jẹ anfaani rẹ.

Alaga ẹgbẹ awọn gomina Naijiria naa tun fi kun ọrọ rẹ pe idunnu nla lo jẹ foun bi ayẹyẹ ọdun Bareke ọhun ṣe lọ, to si ni pataki rẹ ni lati ko gbogbo ọmọ ipinlẹ naa jọ fun ifẹ, iṣọkan ati idagbasoke alailẹgbẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI