Owo ina mọnamọna ni iyaale ile to n t'ọmọ lọwọ fẹ lọ san, ki mọto too tẹ ẹ pa lori ọkada l'Ọṣun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 3, 2023

Owo ina mọnamọna ni iyaale ile to n t'ọmọ lọwọ fẹ lọ san, ki mọto too tẹ ẹ pa lori ọkada l'Ọṣun


Bi ẹlẹkun ṣe n sunkun, bẹẹ l'awọn eeyan n gbera ṣanlẹ lọjọ Ẹti, Furaide to kọja yii, nigba ti mọto ayọkẹlẹ Toyota Camry kan tẹ iyaale ile kan pa lori ọkada.
 
Owo ina ni wọn sọ pe obinrin naa ti ọpọ awọn eeyan mọ si Iyawo Ori Ade fẹẹ lọ san, ko to padanu ẹmi rẹ lori ọkada naa, to si ba awọn eeyan rẹ lọkan jẹ gidi.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, agbegbe Agunbẹlewo ni wọn l'obinrin to padanu ẹmi rẹ ni nnkan bi aago mẹta ọsan, ọjọ naa n gbe n'ipinlẹ Ọṣun
 
Mọto Toyota Camry ti nọmba idanimọ rẹ jẹ KRD 930 HV, ni wọn lo sọ ijanu rẹ nu, to si lọ gba a lori ọkada to gbe. Loju ẹsẹ ni wọn ni ọlọkada naa ti gbọna ọrun lọ.
 
Awọn to wa nibẹ sọ pe awọn ẹlẹyinju aanu ni wọn sare gbe e lọ si ọsibitu Osun State University Teaching Hospital fun itọju, nibi ti wọn lo pada dakẹ si lọjọ keji, iyẹn ọjọ Abamẹta, Satide.
 
Ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ, Sunkanmi Ayodele, lo darukọ awakọ Toyota ọhun gẹgẹ bii Bello Ayọdeji, ẹni to sọ pe o padanu ijanu mọto ọhun lakoko to n lọ sagbegbe Okinni.
 
Ibi to lo ti n wa ọna bi yoo ti da mọto ọhun duro lo ti lọ kọlu ọlọkada ati ero to gbe lẹyin, iyen Iyawo Ori Ade.
 
Yẹmisi Ọpalọla to jẹ agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, bẹẹ lo sọ pe awọn ti fẹẹ ṣayewọ lati mọ iru iku to pa obinrin naa, to si ni ayewọ ọhun ni yoo ran iwadii awọn lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI