Abẹokuta lọwọ ti tẹ Francis, ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn n wa tipẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, July 16, 2023

Abẹokuta lọwọ ti tẹ Francis, ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn n wa tipẹ


Ṣikun bayii lọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun tẹ gendekunrin, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn kan, Francis Okere ti wọn sọ pe ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn ti n wa tipẹ ni.

Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abiọdun Alamutu lo fi idaniloju yii mulẹ ni olu ileeṣẹ wọn to wa ni Eleweran niluu Abẹokuta laipẹ yii, iyẹn lakoko to n foju awọn afurasi ọdaran tọwọ tẹ kaakiri ipinlẹ Ogun han f’awọn akọroyin.

Alamutu sọ pe ọwọ tẹ Francis latari olobo to ta si wọn leti wi pe ikọ ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ti sapamọ sinu ile kan to wa lagbegbe Kemta si Ṣomọrin niluu Abẹokuta.

O ni ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiyee ni wọn pe wọn, to si loju ẹsẹ lawọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii, ko to di pe ọwọ palaba wọn segi lọjọ kẹfa, oṣu keje, ọdun yii.

Nibẹ lo ti sọ pe bi awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii ṣe ri ikọ ọlọpaa to n gbogun ti iwa ẹgbẹ okunkun ni wọn ti gbiyanju lati salọ, ṣugbọn ti ọwọ si tẹ Francis.

Ibọn ilewọ gigun kan, ati ọta ibọn mẹta ọtọọtọ ni wọn gba lọwọ ẹ loju ẹsẹ, to si tun n bẹbẹ nibẹ pe ki wọn da aṣọ aṣiri bo oun.

Wọn ni bọwọ ṣe tẹ ẹ, lo ti bẹrẹ sii jẹwọ wi pe ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun aake dudu ‘Black Axe’, ti wọn tun n pe ni Aiye loun, ati pe oun ti wa lẹnu rẹ tipẹ, to si loun ṣetan lati fẹgbẹ buruku naa silẹ, bi wọn ba le foju aanu wo oun.

Alamutu ninu ọrọ rẹ ṣalaye pe ile-ẹjọ nikan lo le dariji Francis, nitori pe awọn yoo foju rẹ ba ile-ẹjọ lẹyin ti iwadii ba tubọ pari.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI