Ọlayinka at’awọn ọrẹ rẹ ha ni Ṣagamu, ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun ni wọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, July 16, 2023

Ọlayinka at’awọn ọrẹ rẹ ha ni Ṣagamu, ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun ni wọn


Boroboro l’awọn ọrẹ mẹta kan tọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun tẹ laipẹ yii niluu Ṣagamu n ka, nigba tọwọ palaba wọn segi, ti wọn si tun n ṣeleri wi pe awọn yoo yi pada si rere.

Ogunkọya Ọlayinka, ẹni ọdun mẹtalelogun; Awotungaṣe Samson, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn; ati Abalọ Ayọmide toun jẹ ọmọ ogun ọdun l’awọn mẹtẹẹta ti a gbọ pe ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun paraku ti wọn n da ilu Ṣagamu ati agbegbe rẹ laamu ni wọn.

Gẹgẹ bi ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abiọdun Alamutu ṣe sọ lakoko to n foju awọn ọdaran naa han f’awọn akọroyin niluu Abẹokuta, o sọ pe awọn mẹta yii wa lara awọn to ṣeku paayan lọjọ keje, oṣu keje, ọdun 2023 lagbegbe Batọrọ to wa niluu Ṣagamu

Nibẹ lo ti sọ pe awọn gba ibọn ilẹwọ agbelẹrọ ẹlẹnu meji ati ẹlẹnu kan, to fi mọ ọta ibọn kan ṣoṣo ati oogun abẹnugọngọ lọwọ wọn.

Ọga ọlọpaa naa ṣeleri wi pe awọn tọwọ tẹ yii yoo foju ba ile-ẹjọ lẹyin ti iwadii ba tubọ pari.

Bakan naa lo gba awọn araalu lamọran lati pariwo awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun tabi afurasi ọdaran ti wọn ba kofiri lagbegbe wọn sita faraye, ki ọwọ le tete tẹ wọn ko to di pe wọn ṣiṣẹ ibi ti yoo pa wọn lara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI