Aralọla lo yẹ ki wọn maa pe ni 'Idan Gangan' - Awọn oyinbo fontẹ lu Aralọla, gbajumọ onilu agbaye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 19, 2023

Aralọla lo yẹ ki wọn maa pe ni 'Idan Gangan' - Awọn oyinbo fontẹ lu Aralọla, gbajumọ onilu agbaye


Ti wọn ba sọ pe idan gangan, ko si ẹlomi-in ti wọn n sọ to ju aṣaaju awọn obinrin onilu, Arabinrin Ṣẹrifat Ọlamuyiwa ti gbogbo aye mọ si Aralọla lọ. Idi ni pe arẹwa obinrin naa ti fi Ilu ati orin dara laarin awọn oyinbo alawọ funfun.


Ṣe L'awọn oyinbo ati dudu la ẹnu silẹ, ti wọn ko le e pa a de, nigba ti wọn ri ara nla ti Aralọla fi ilu da lara, ni gbogbo wọn ba n pariwo pe 'idan gangan ree o', wọn l'awọn ko ri iru idan ti Ara pa yii lati ọjọ t'awọn ti de ile aye.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, orileede Spain lọhun-un ni Aralọla ti gb'orukọ orileede yii ga, ti obinrin naa jẹ k'awọn dudu ati oyinbo mọ pe Ọlọrun jo'gun ẹbun nla fun Iran Yoruba. 


Lara awọn ayẹyẹ ti wọn ṣe ni Spain ti Aralọla ti dabira ni: Fuertventuraenmusica festival, Etnosur festival 
Imaginafunk festival 
Folkdelmundo festival 
CanariasJazz festival 
Canariasjazz festival 
Sinsal festival atawon mi-in.

Awọn ilu ti Aralọla ti fakọyọ ni: Fuertventura, Grand Canaria, Jean, Algaceria, Granada.


Nitori itu meje ti ọdẹ n pa ninu igbo ti Aralọla pa yii, l'awọn eeyan kan fi sọ pe ẹbun ti awọn eeyan wa ni Naijiria ko mọ iyi rẹ ni awọn oyinbo gbe oṣuba rabandẹ-rabandẹ fun yii, wọn ni iyi ati apọnle ti ko si fun ẹbun wa la a ṣe padanu ẹbun nla bii Ṣade Adu ati Aṣa ṣọwọ awọn oyinbo.

Ju gbogbo ẹ lọ, awọn oyinbo ti sọ pe Aralọla lo yẹ ki wọn maa pe ni Idan gangan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI