Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina Abdulrahman AbdulRazaq ti kede gbogbo ọjọ akọkọ ninu iwe onka awọn Musulumi kaakiri agbaye gẹgẹ bi ọlude fun gbogbo awọn eeyan, paapaa awọn oṣiṣẹ ijọba.
Gomina AbdulRazaq sọ pe ọjọ akọkọ naa l'awọn musulumi n pe ni, to si l'awọn musulumi ti n beere tipẹ fun ọlude lati maa fi dupẹ lọwọ Ọlọrun wọn.
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye gbe jade, lo ti sọ pe gomina gba awọn musulumi lamọran lati maa lo akoko naa fun ifarada ati iṣọkan.
“Gomina ti ṣagbeyẹwọ ohun ti awọn eeyan kaakiri n beere fun igba pipẹ. O ti wa a buwọ luu pe ki ọlude maa wa lọdọọdun, gẹgẹ bo ṣe n ṣẹlẹ l'awọn ipinlẹ yooku lorileede yii. Fun idi eyi, Ọjọru, Wẹsidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu keje, 2023 to jẹ ọjọ akọkọ ninu iwe onka Isilaamu (Muharram 1445), yoo jẹ ọlude n'ipinlẹ naa”.
No comments:
Post a Comment