Ẹ mai tii kanju, igbesẹ ọmọ kekere igbagbọ ni mo n gbe - Tinubu rọ awọn ọmọ Naijiria - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 1, 2023

Ẹ mai tii kanju, igbesẹ ọmọ kekere igbagbọ ni mo n gbe - Tinubu rọ awọn ọmọ Naijiria


Aarẹ orileede Naijiria, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu ti gba gbogbo awọn ọmọ ati olugbe orileede yii lamọran lati ṣe suuru foun ninu eto iṣejọba oun bẹrẹ lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2023.

O ni ohun gbogbo lo ṣi maa bọ soju ẹ gẹgẹ bi ireti awọn araalu, ti wọn yoo si gbadun mudunmudun eto oṣelu awarawa.

Aṣiwaju Tinubu lo sọrọ yii niluu Abẹokuta, lakoko abẹwo to ṣe lọ sọdọ Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Michael Adedọtun Arẹmu Gbadebọ.

Ṣaaju asiko yii ni Aarẹ Tinubu yi kọkọ lọ si ilu Ijẹbu-Ode, lọdọ ọba alaye ilẹ Ijẹbu, Ọba Sikirulai Adetọna, Awujalẹ.

Tinubu sọ pe k'awọn ọmọ Naijiria maa tẹle oun ninu ilana to pe ni 'igbesẹ ọmọde igbagbọ (baby steps of faith), to si loun ṣeleri lati mu gbogbo ileri oun lasiko ipolongo idibo ṣẹ fawọn araalu mm

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe 
"Ẹ jẹ ka tẹle igbesẹ ọmọde igbagbọ yii. Mo n lo ilana ọmọ kekere igbagbọ ni mo n lo gẹgẹ bi aarẹ. Ẹ ma ṣe jẹ ka kanju. Ẹ gbaradi fun ohun to fẹẹ ṣẹlẹ. Ẹ jẹ ki itura itusilẹ maa kaakiri na. Ẹ jẹ ki igboya yẹn pada. 

"Orileede yii nikan la ni. Mo ti figba kan ri jẹ ẹni to n sa asala, mo si mo nnkan to tunmọ si.

"Nigba ti adura wa, 'Emi lo kan' ti gba, ohun ti mo n beere fun bayii ni adura fun Naijiria. Mo ti pinnu lati ran orileede yii lọwọ lati gbe ọkọ orileede yii dide, ki n si mu awọn ileri mi lasiko oṣelu ṣẹ.

"Mo wa sibi lati mu lara awọn ileri mi ṣẹ. Ko si iyatọ kankan laaarin awa ati awọn araalu. Mo sọ eyi lorileede France wi pe mọlẹbi kan naa la jẹ, ti a si n gbe ninu ile kan naa, bo tilẹ jẹ pe yara ọtọọtọ la n sun si.

"Ẹ jẹ ka wa ni iṣọkan, oṣuṣu ọwọ lai gbọ ariwo ọja. Ebute ayọ rere ni gbogbo wa maa pada ja si. Ojuṣe gbogbo wa ni lati fi itan balẹ. Lagbara Ọlọrun, a maa kore iṣẹ ọwọ wa. Naijiria yoo ri ayipada rere.

"Ẹ dakun, a nilo awọn adura yin, a nilo igbarukuti yin, a nilo idasi yin ki eto ọrọ aje orileede yii le ṣina rere fun gbogbo yin si daadaa"

Bakan naa lo sọ erongba ohun ni lati yọ wọ ipinlẹ Ogun, ṣugbọn lai mọ pe ko ṣee ṣe, to si loun ṣẹṣẹ mọ bi ipo Aarẹ toun di mu bayii ṣe ri ni.

“Mo pinu lati wa sibi, ki n si dupẹ oore lọwọ awọn olori wa, Ọba Gbadebọ ati gbogbo awa ti a wa nibi. Arẹmọ Oluṣẹgun Ọṣoba, ẹ ku iṣẹ; Dimeji Bankọle, mo ki ẹ, Abikunlẹ Amosun, ẹ ku iṣẹ. Alaga ẹgbẹ, mo dupẹ; Mo dupẹ nitori pe bi ko tiẹ si owo, paap bi nnkan ṣe le koko to, a dide lati ṣe ojuṣe wa, mo gbe o'suba fun un yin.

“Abẹwo mi yii, mi o mọ pe bo ṣe maa ri ree. Mo ro pe ki n yọ wa, ki n si yọ pada ni; ṣugbọn ni bayii, mo ti wa mọ ohun ti ipo aarẹ jẹ. Ohun to dara ni.

“Nibi ni ireti naa ti dide. Ireti naa ko nii kuna. Ireti naa yoo mu ki ina yn tan sii."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI