Gbogbo agbaye ni yoo maa wọ ipinlẹ Kwara wa fun irin ajo afẹ - AbdulRazaq ṣeleri - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 3, 2023

Gbogbo agbaye ni yoo maa wọ ipinlẹ Kwara wa fun irin ajo afẹ - AbdulRazaq ṣeleri


L'opin ọsẹ to kọja yii ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ṣeleri fun ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa wi pe oun yoo tubọ maa gbaruku ti eto irin ajo afẹ fun idagbasoke ipinlẹ wọn.
 
AbdulRazaq ni atunṣe yoo de ba eto ọhun ni pẹrẹu, koda ti awọn arin-rin-ajo kaakiri agbaye yoo maa wa si ipinlẹ naa fun irin ajo afẹ wọn, eyi ti yoo mu ki eto ọrọ aje wọn tun adagbasoke sii.
 
Gomina sọrọ yii nibi ayẹye ọlọdọọdun 'Sallah Nkọ' to waye niluu Lafiagi, ijọbha ibilẹ Edu.
 
Nibẹ lo ti sọ pe ọlọrun fi oriṣiriṣi eto Aṣa ajogunba ta ipinlẹ naa lọrẹ, paapaa fun irin ajo afẹ, f'awọn eeyan kaakiri agbaye lati mọ, eyi ti awọn yoo mu idagbasoke ba eto ọrọ aje wọn.

Ayẹyẹ ọdun "Sallah Nkọ" yii la gbọ pe awọn ọmọ ilu Lafiagi maa n ṣe lọdọọdun lati fi ṣajọyọ, ti wọn yoo tun lọ si Aafin Ẹmir wọn, iyẹn lasiko ọdun Ileya.
 
Nibi ayẹyẹ t'ọdun yii ni wọn ti we Lawaani fun awọn to ti laami laaka niluu naa, ti wọn si n ko ipa ribiribi lawujọ.
 
AbdulRazaq nigba to n sọrọ, ṣalaye pe
"A ma maa tẹsiwaju lati gbe Aṣa wa larugẹ ni. L'ọdun to n bọ, a tun maa ṣe ju bayii lọ. A fẹ ki awọn ọmọ Naijiria maa wa siluu Lafiagi, gẹgẹ bi wọn ṣe n wa si Durbar Ilọrin. Papakọ ofurufu wa nibi, eyi ti yoo jẹ ki ẹ fo wọle, ki ẹ si tun fo jade.

"Iwaasu wa ni gbogbo igba lo n mu alaafia ati idagbasoke dani. Ọpọ awọn eeyan ni wọn ti bu ọla ati iyi fun nitori pe ipa ti wọn nko lawujọ, niluu ati kaakiri."
 No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI