Iroyin ẹlẹjẹ lasan ni, AbdulRazaq ko ni k'awọn ọba yago f'awọn oloṣelu alatako ni Kwara - Ọlọfa tiluu Ọffa pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 3, 2023

Iroyin ẹlẹjẹ lasan ni, AbdulRazaq ko ni k'awọn ọba yago f'awọn oloṣelu alatako ni Kwara - Ọlọfa tiluu Ọffa pariwo sita


Ọlọfa tiluu Ọffa, Ọba Mufutau Gbadamọsi Eṣuwoye, ti sọ pe iroyin ẹlẹjẹ ti ko ni otitọ kankan ninu ni b'awọn kan ṣe n gbe e kaakiri wi pe Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti paṣẹ f'awọn ọba alaye nipinlẹ Kwara lati yago f'awọn oloṣelu alatako.
 
Kabiyesi ni irọ to jinna patapata si otitọ ni iroyin t'awọn kan n gbe kaakiri, to si jẹ ko di mimọ pe awọn ọta ipinlẹ naa lo wa nidii iroyin ọhun.

O ni gbogbo awọn ọba ti wọn n sọ pe Gomina AbdulRazaq ti ni k'awọn maa yago f'awọn oloṣelu alatako kan n wa ọna atijẹ lasan ni, nitori pe wọn ko sọ otitọ.
 
Kabiyesi naa lo sọrọ yii lọjọ Ẹti tii ṣe Furaidee, ọsẹ to kọja yii, lakoko to n gba Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba lorileede yii tẹlẹri, Sẹnetọ Bukọla Saraki ati iyawo rẹ lalejo ni aafin rẹ to wa niluu Ọffa.

Saraki ati iyawo rẹ ni wọn lọ siluu Ọffa lati ba mọlẹbi Ọyawoye ati gbogbo araalu kẹdun iku gbajumọ Ọjọgbọn Jimọh Ọyawoye.

Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni iroyin kan n lọ kaakiri ori ikaani ayelujara wi pe Gomina  AbdulRazaq ti paṣẹ fun gbogbo awọn ọba lati ma ṣe gba awọn oloṣelu alatako lalejo ni aafin wọn, ati pe wọn ko gbọdọ ni ohunkohun lati ṣe pẹlu wọn.
 
Ko si nnkan to fa a bi ko ṣe pe Saraki lo s'ijọba ibilẹ Kwara North, to si ya ni aafin Etsu tiluu Patigi ati Emir tiluu Tsaragi, ṣugbọn ti ori ade naa ko si nitosi lati gba a lalejo.
 
Ṣugbọn nigba to n sọrọ, Ọba Mufutau Eṣuwoye, to pa irin ajo rẹ ti lati gba Saraki lalejo sọ pe aṣẹ kankan ko wa lati ọdọ gomina, ati pe awuyewuye lasan ni wọn n gbe kaakiri.
 
“Nigba ti wọn sọ fun mi pe Sẹnetọ Bukọla Saraki n bọ niluu Ọffa lonii, mo ti ni eto miran nilẹ tẹlẹ, ṣugbọn mo ni lati pa a ti ni, ki n le gba a lalejo.
 
“Idi ni pe awọn eeyan tun le gbe awuyewuye jade wi pe boya gomina ipinlẹ Kwara, Malaam Abdulrahman Abdulrazaq lo ti paṣẹ rẹ wi pe awọn ọba ko ba alatako ṣe.
 
“Ṣugbọn ki n sọ otitọ fun un yin, gomina ko sọ fẹnikẹni wi pe wọn ko gbọdọ ba awọn alatako ṣe nipinlẹ naa. Awọn ọba to ba ṣe bẹẹ, kan n ṣe e ni ti ara wọn lasan ni.”
 
Kabiyesi ni awọn ijọba to wa ni ipo agbara ni ọba jẹ, ati pe awọn ọba to n salọ f'awọn oloṣelu alatako ko ṣe otitọ pẹlu ara wọn, nitori pe wọn ko mọ ohun to n bọ lọjọ iwaju.
 
Nibẹ lo ti gbe oriyin to si dupẹ lọwọ Saraki ati iyawo rẹ, ati Amofin Toyin Ọjọra-Saraki fun abẹwo wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI