Koffi, ọmọ Togo fi aṣọ ọlọpaa ji baagi simenti kan gbe n'Ile-Ifẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 8, 2023

Koffi, ọmọ Togo fi aṣọ ọlọpaa ji baagi simenti kan gbe n'Ile-Ifẹ


Ṣikun bayii lọwọ ẹṣọ aabo Amọtẹkun, ẹka t'ipinlẹ Ọṣun tẹ baba agbalagba, ọmọ ilẹ Togo kan, John Apata Koffi lori ẹsun ole jija ti wọn fi kan an.
 
Baagi Simẹnti kan ṣoṣo la gbọ pe Koffi ati Isaiah Friday Ezekiel, toun jẹ ọmọ ipinlẹ Cross Rivers jigbe niluu Ile-Ifẹ, ipinlẹ naa.
 
Koffi, ẹni aadọta ọdun ati Ezekiel toun jẹ ẹni ọdun mọkanlelogoji la gbọ pe aṣọ ọlọpaa ni wọn lọ fi ji baagi simẹnti ọhun gbe labule Eleweran Kajọla, niluu Ile-Ifẹ, ko to di pe ọwọ Amọtẹkun tẹ wọn l'ọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ yii.
 
Gẹgẹ bi Ọgagun Bashir Adewinmbi, to jẹ olori aabo Amọtẹkun nipinlẹ naa ṣe ṣalaye f'awọn akọroyin, o sọ pe awọn kan lo wa fi ẹjọ sun awọn ẹṣọ wọn ni Ifẹ, ti wọn si dide lati ṣe iwadii.
 
Ninu iwadii lọwọ ti tẹ Koffi ati Ezekiel, ati pe wọn tun gba fila ọlọpaa, ayederu ibọn ati oogun abẹnugọngọ lọwọ wọn.
 
Adewinmbi wa jẹ ko di mimọ pe awọn ti lọ fa awọn mejeeji naa le awọn ọlọpaa lọwọ lati ṣewadii kikun lori wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI