O ku dẹdẹ ki ọmọ ọdun mẹtadinlogun ṣe idanwo WAEC, ni alaaganna ba gun-un pa l'Ondo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 8, 2023

O ku dẹdẹ ki ọmọ ọdun mẹtadinlogun ṣe idanwo WAEC, ni alaaganna ba gun-un pa l'Ondo


Niṣe ni ariwo ati ẹkun ibanujẹ sọ lagbegbe Arogbo to wa nijọba ibilẹ Ẹsẹ-Odo, ipinlẹ Ondo, nigba ti wọn ri bi alaaganna kan ṣe pa ọmọdekunrin, akẹkọọ kan, Timibra Meretighan danu.
 
Timibra, ọmọ ọdun mẹtadinlogun naa ni wọn lo n palẹmọ idanwo aṣekagba rẹ nile ẹkọ girama, eyi ti a mọ si WAEC lọwọ, ko to di pe o kagbako iku ojiji.
 
Ile-ẹkọ girama ti Ijaw National High School to wa lagbegbe Arogbo ni wọn sọ pe Timibra n lọ, to si wa ni ipele aṣekagba ti a mọ si SSS3.
 
Gẹgẹ bi ọkan lara awọn tiṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn ṣe sọ, wọn ni alaaganna ọhun lo wọnu ọgba ile-ẹkọ ti Timibra n lọ lasiko ti ojo n rọ lọwọ.
 
Asiko naa ni wọn l'awọn akẹkọọ bẹrẹ sii fi ṣe ẹlẹya, eyi ti wọn loo bii ninu, to fi di pe o kọju ija si wọn lojiji.
 
Wọn ni ibi ti alaaganna naa ti n le awọn akẹkọọ yii kaakiri lo ti rọwọ to Timibra, ko to di pe o gun un pa.
 
Gbogbo agbegbe yii ni wọn sọ pe iṣẹlẹ naa ṣe ni kayeefi pupọ, to si ba wọn lọkan jẹ gidi.
 
Nigba to n sọrọ, agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, Funmilayọ Ọdunlami-Omisanya, ṣalaye pe ọga ileewe naa lo wa sọ ohun to ṣẹlẹ ni teṣan wọn, ti wọn fi debẹ.
 
O sọ pe ọga ileewe ọhun ni ọkunrin naa to pe orukọ rẹ ni Oke Loya, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn lo fo fẹnsi wọnu ọgba, to si gun akẹkọọ awọn pa.
 
Ọdunlami ti wa fidi rẹ mulẹ pe ọwọ awọn ti tẹ ọkunrin naa, o si ti wa lahamọ awọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI