Lẹyin ti ọkọ ọga rẹ fipa ba a laṣepọ, ọmọdun mẹrindinlogun gb'ẹmi ara rẹ l'Eruwa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 1, 2023

Lẹyin ti ọkọ ọga rẹ fipa ba a laṣepọ, ọmọdun mẹrindinlogun gb'ẹmi ara rẹ l'Eruwa


Ariwo ati ẹkun ikunlẹ abiyamọ lo gba ẹnu awọn ara agbegbe Eruwa to wa nijọba ibilẹ Ibarapa, ipinlẹ Ọyọ laipẹ yii, nigba ti wọn gbọ aṣiri idi ti ọmọ ọdun mẹrindinlogun kan, Ọlayẹmi Agbẹlọba fi deedee gb'ẹmi ara rẹ lojiji.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn niṣe nu Ọlayẹmi fibinu gbe majele jẹ lẹyin ti ọkọ ọga rẹ, Ọgbẹni Ajibọde fipa ba a laṣepọ karakara, to si tun dunkooko mọ wi pe oun yoo pa a danu, to ba fi le tu aṣiri naa sita.
 
A gbọ pe inu oṣu kin-in-ni, ọdun yii ni Ọlayẹmi de ọdọ iyawo Ajibọde ti wọn loun n ṣiṣẹ tẹlọ, iyẹn awọn to n ran aṣọ. Wọn ni awọn obi rẹ lo lọ fa a le lọwọ lati le kọ iṣẹ naa, ati pe to ba n gbe lọdọ wọn, yoo tete mọ iṣẹ naa daadaa.
 
Wọn ni laipẹ yii ni Ajibọde f'ipa ba ọmọ naa laṣepọ, to si tun dunkooko iku mọ ọn, idi ree ti wọn lo fi fibinu gbe majele jẹ, nitori ibẹru to ti wa lọkan rẹ.
 
Nigba to n sọrọ, baba ọmọ naa, Ọgbẹni Sunday Agbẹlọba sọ pe ẹdun ọkan lo jẹ f'oun nigba toun gbọ nipa nnkan to ṣẹlẹ, to si loju ẹsẹ loun ti lọ fi iṣẹlẹ ọhun to awọn ọlọpaa leti.
 
Ọkunrin naa kọminu lori bo ṣe l'awọn ọlọpaa fi Ajibọla silẹ lati maa lọ, to si ni niṣe ni Ajibọla n buga kaakiri wi pe ko sẹni to le mu oun, nitori toun ti fi eeyan mimọ ṣọrọ.
 
“Ibẹrẹ ọdun yii ni Ọlayẹmi lọ sile awọn iyawo Ajibọde lati maa ba a ṣiṣẹ to ba fẹẹ ṣe nile, paapaa lati tun le tete mọ iṣẹ telọ to lọ kọ nibẹ. Oṣu kẹfa ree to ti n gbe pẹlu wọn, to si jẹ pe lojiji ni wọn sọ fun wa pe o ti ku.
 
“Igba to ya la tun n gbọ pe Ajibọde lo f'ipa ba a laṣẹpọ, idi pataki to fi gbe majele mu. Awọn oniṣegun oyinbo lo tu aṣiri naa fun wa lọsibitu ti wọn gbe e lọ fun itọju. Wọn lo jẹwọ fun wọn nibẹ ko too ku.

“Mo wa lọ teṣan ọlọpaa Eruwa lati fi to wọn leti, wọn gbe e, ṣugbọn niṣe ni wọn tun fi silẹ. Latigba naa ni Ajibọde ti n pariwo kaakiri pe oun mọ awọn eeyan, ko si nnkan ti wọn le ṣe f'oun. O f'ipa ba ọmọ mi laṣepọ, eyi to jẹ kiyẹn pa ara rẹ, o si tun n rin kaakiri laaarin ilu.”
 
Agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa Ọyọ, DSP Adewale Ọṣifẹsọ  nigba toun n sọrọ, o ni iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa, ati pe oun yoo sọrọ nigba ti awọn ba tubọ ṣewadii siwaju sii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI