Nitori ọwọngogo epo: AbdulRazaq fi ẹgbẹrun mẹwaa naira kun owo oṣu awọn oṣiṣẹ gẹgẹ bi owo iranwọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 24, 2023

Nitori ọwọngogo epo: AbdulRazaq fi ẹgbẹrun mẹwaa naira kun owo oṣu awọn oṣiṣẹ gẹgẹ bi owo iranwọ


Niṣe ni idunnu ṣubu lu ayọ gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba patapata kaakiri ipinlẹ Kwara, nigba ti ijọba ipinlẹ naa kede sita wi pe Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti buwọ lu ẹgbẹrun mẹwaa naira gẹgẹ bi owo iranwọ lori owo oṣu gbogbo awọn oṣiṣẹ kaakiri ipinlẹ naa.

Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lo gbe igbesẹ yii lati mu irọrun ba gbogbo awọn oṣiṣẹ jakejado lori ọwọngogo epo rọbii to n ṣẹlẹ lasiko yii, eyi to jẹ ki owo gbogbo nnkan lọ soke lojiji.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye gbe jade lonii, o f'idi rẹ mulẹ pe igbayegbadun araalu, paapaa awọn oṣiṣẹ jẹ gomina logun, idi ree to fi buwọ lu owo iranwọ naa.

Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ pe gomina ti sọ pe oun n reti lati fi owo kun owo oṣu gbogbo oṣiṣẹ patapata, iyẹn bi ijọba apapọ ba ti bu ọwọ lu gbedeke ẹkunwo owo oṣu kaakiri Naijiria.
 
Ajakaye sọ pe ipari oṣu keje, ọdun ti a wa yii ni ijọba Kwara yoo bẹrẹ si i san awọn owo naa, iyẹn ẹgbẹrun mẹwaa naira.

Siwaju sii lo fi kun ọrọ rẹ pe sisan owo iranwọ ẹgbẹrun mẹwaa naira yii yoo d'opin nigba ti ijọba apapọ ba ti buwọ lu owo oṣu tuntun f'awọn oṣiṣẹ jakejado Naijiria.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI