Gomina Kwara ṣabẹwo lọ sọdọ olori ẹgbẹ awọn afọju n'Ilọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 24, 2023

Gomina Kwara ṣabẹwo lọ sọdọ olori ẹgbẹ awọn afọju n'Ilọrin


Lojuna lati maa na ọwọ ifẹ ati iṣọkan s'awọn araalu, gomina ipinlẹ Kwara AbdulRahman AbdulRazaq tun ti ṣabẹwọ si olori ẹgbẹ awọn afọju n'ipinlẹ naa, iyẹn Seriki Mekafo, Alaaji Mohammed Salihu.
 
Ọjọ Aiku, Sannde to kọja yii ni Gomina AbdulRazaq ṣe abẹwo naa, lati ṣeleri igba ọtun ati ijọba mẹkunnu fun wọn.
 
Buba awọn afọju naa to wa nibi ti wọn n pe ni Koro Afọju, iyẹn lagbegbe Gambari, ilu Ilọrin ni gomina ti lọ ṣabẹwo si wọn.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI