O ma ṣe o! Eeyan mẹwaa ṣofo ẹmi ninu ijamba ọkọ ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 15, 2023

O ma ṣe o! Eeyan mẹwaa ṣofo ẹmi ninu ijamba ọkọ ni Kwara


Ko din ni eeyan mẹwaa ọtọọtọ ti wọn jade laye nibi ijamba ọkọ to waye lopopona marosẹ Bode Saadu si Jebba to wa n'ijọba ibilẹ Moro, ipinlẹ Kwara l'ọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ ti a wa yii.
 
Awọn mẹtadinlogun la gbọ pe wọn fara kaaṣa ninu ijamba naa, ṣugbọn to jẹ pe awọn mẹwaa lo gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra, nigba ti awọn yooku farapa yannayanna.
 
Lara awọn to fi iṣẹlẹ ọhun to wa leti sọ pe nnkan bi aago mẹfa aabọ aarọ ni ijamba ọhun waye lagbegbe abule Ilupupa, ti wọn si ni ọkunrin meje, obinrin kan ati awọn ọmọdebinrin meji ni wọn ku sinu ẹ.
 
Bakan naa ni wọn fi to wa leti pe mọto mẹta ọtọọtọ ni wọn fara kaaṣa.
 
Nigba to n fidi iroyin ọhun mulẹ, Frederick Ade Ogidan to jẹ alaoko eto irinni fun ileeṣẹ ẹṣọ aabo oju popona tijọba apapọ, Federal Road Safety Corps, FRSC jẹ ko di mimọ pe owo to din diẹ ni ẹgbẹrun mọkanlelọgọta, N60,750 naira l'awọn ri lakoko ijamba naa.
 
Ogidan ni ko si nnkan to fa ijamba ọhun, bi ko ṣe ere asapajude, ati igbiyanju lati ya ọkọ to n lọ kọja.
 
Nibẹ lo ti darakọ awọn mọto naa bii Volkswagen Sharan, alawọ ewe ti nọmba idanimọ rẹ jẹ AKD 733FX; mọto alawọ goolu ti nọmba idanimọ rẹ jẹ GWA 22DD; ati mọto akero ti nọmba idanimọ rẹ jẹ DTS 139XA.
 
Ogidan lawọn ti ko awọn oku naa lọ si mọṣuari ọsibitu Ilọrin, nigba ti wọn ko awọn to farapa lọ si ọsibitu Shalom to wa ni Bode Saadu.
 
Bẹẹ lo tun fi kun un wi pe gbogbo awọn mọto naa ni wọn ti wa lọgba ọlọpaa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI