Adura mi ni pe ki emi ati iyawo mi ku lọjọ kan naa - Pasitọ Adeboye ju bọmbu sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 15, 2023

Adura mi ni pe ki emi ati iyawo mi ku lọjọ kan naa - Pasitọ Adeboye ju bọmbu sita


Ọpọ awọn eeyan lo lanu silẹ, ti wọn ko si le pa a de, nigba ti alaṣe ati olori ijọ Redeemed Christian Church of God, Pasitọ Enoch Adejare Adeboye, sọ pe gbogbo adura ati ifẹ ọkan oun ni lati jade laye lọjọ kan ṣoṣo pẹlu iyawo oun, Folu Adeboye.

Iyalẹnu nla ti ẹnikẹni ko lero ni Pasitọ Adeboye, ti ọpọ tun n pe ni Daddy G.O sọ jade, to si mu k'awọn eeyan maa sọ oriṣiriṣi nipa ọrọ ọhun.
 
Baba Adeboye lo sọrọ lori ikanni ayelujara ti Twitter rẹ l'Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, ọsẹ ti a wa yii, iyẹn lakoko to n ṣayẹyẹ ọdun karundinlọgọrin ti iyawo rẹ, Pasitọ Arabinrin Folu Adeboye ṣe.

O ni Ọlọrun lo fi iyawo oun ta oun lọrẹ nla, ati pe ibukun nla toun ri gba lọwọ Ọlọrun ni iyawo oun.
 
“Ju gbogbo rẹ lọ, igbala ọkan mi ati ibantisi ti Ẹmi Mimọ, ẹbun nla pataki ti Ọlọrun fi ta mi lọrẹ ni iyawo mi, @pastorfoluadeboye.
 
“Ohun to han gbangba daju ni pe ẹni to ba gboju-gboya lati sọ pe oun fẹẹ ṣe iyawo mi ni jamba, yoo koju ija lati oke wa. Ọpọ awọn eeyan ni ko mọ ipele itara rẹ, ifẹ ati iwa ọmọluabi to ni s'awọn eeyan.
 
“Latigba to ti pinnu lati lo eyi to ku aye rẹ pẹlu mi, o ti duro ti mi lasiko didara ati lasiko aidara, lasiko ọpọ ati aisi. Lara awọn adura takuntakun ti mo maa n gba fun awa mejeeji ni pe ka pada sile papọ nigba ti akoko ba to.
 
“A ni awọn orukọ didun ti a maa n pe ara wa. Mo n pe gbogbo eeyan lati darapọ mọ mi ṣajọyọ obinrin to fẹran lati maa pariwo 'Hallelujah' nibikibi ti ẹ ba wa. Api baide, ololufẹ mi ọwọn @pastorfoluadeboye.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI