O pari! Wọn ju Ayanrinde sẹwọn ọdun mẹta l'Oṣogbo, iṣẹ agbẹjọro lo fi n lu jibiti - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 15, 2023

O pari! Wọn ju Ayanrinde sẹwọn ọdun mẹta l'Oṣogbo, iṣẹ agbẹjọro lo fi n lu jibiti


Ileeṣẹ eleto aabo ara ẹni laabo ilu ti a mọ si Nigeria Security and Civil Defence Corps (NSCDC), ẹka t'ipinlẹ Ọṣun ti sọ pe aṣeyọri nla l'awọn ṣe lati rii pe idajọ ododo waye lori gendekunrin, ẹni ọdun marundinlọgbọn kan, Ayanrinde AbdulGafar to n fi iṣẹ agbẹjọro lu awọn araalu uni jibiti, iyẹn lori bi ile-ẹjọ ṣe juu sẹwọn ọdun meta gbako pẹlu iṣẹ aṣekara.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni AbdulGafar ko niṣẹ meji ju jibiti, ati pe iṣẹ agbẹjọro lo fi n gba owo lọwọ awọn eeyan, to si tun n fi iṣẹ ọhun jale, pẹlu bo ṣe jẹwọ pe oun ti jale foonu towo rẹ din diẹ ni idaji miliọnu kan naira, N450,000.

Wọn ni niṣe ni Abdulgafar n pe ara rẹ ni ọkan lara awọn agbẹjọro agba lorileede Naijiria, iyẹn Senior Advocate of Nigeria, SAN f'awọn to ba fẹẹ lu ni jibiti.
 
Agbẹnusọ fun ẹṣọ aabo Sifu Difẹnsi nipinlẹ naa, ASC Adeleke Kẹhinde nigba to n sọrọ ṣalaye pe awọn kan ti AbdulGafar lu ni jibiti lo wa fi to wọn leti, ti wọn si bẹrẹ iwadii lori ẹ, ko to di pe wọn foju rẹ ba ile ẹjọ.
 
Wọn ni obitibi owo ni ọmọkunrin naa ti gba lọwọ awọn eeyan, ti ko si ni ṣiṣẹ kankan fun wọn.
 
Kẹhinde sọ pe nigba ti adajọ ile-ẹjọ Majisireeti n gbe idajọ kale, o paṣẹ pe k'awọn ko gbogbo owo ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira to wa lapo ifowopamọ si rẹ kuro, ki wọn si ko o f'awọn to lu ni jibiti.
 
Bẹẹ lo sọ pe inu awọn dun wi pe ẹwọn ọdun mẹta gbako ni ile-ẹjọ naa juu si.
 
Siwaju sii lo fi kun un pe Onidajọ ọhun tun paṣẹ pe ki AbdulGafar ni anfaani si ẹkọ imọ iwe lakoko ba fi wa lẹwọn

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI