Ogbologbo olori awọn adigunjale ha sọwọ ẹṣọ aabo So-Safe Corps l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 15, 2023

Ogbologbo olori awọn adigunjale ha sọwọ ẹṣọ aabo So-Safe Corps l'Ogun


Ileeṣẹ eleto aabo ipinlẹ Ogun ti a mọ si So-Safe Corps ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ ogbologbo ọkunrin kan to jẹ olori ikọ awọn adigunjale n'ipinlẹ naa, to si ti n ka boroboro.
 
Ọbani Desmond, ẹni ọdun mejilelọgbọn ni wọn pe ọkunrin naa tọwọ tẹ, ti wọn si tun gba ibọn mẹrin ọtọọtọ ati ọta ibọn loriṣiriṣi lọwọ ẹ.
 
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ eleto aabo naa, Mọruf Yusuf to gbe iroyin ọhun sita ṣalaye pe nnkan bi aago mẹwaa aarọ, Ọjọru tii ṣe Wẹsidee, ọsẹ yii lọwọ tẹ Desmond, ẹni to n gbe lojule karundinlọgbọn, adugbo Agunbiade, Orija, Abule-Iroko, ijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta.

Yusuf sọ pe asiko ti Desmond n gbiyanju lati ja ile kan to wa ni ojule keji, adugbo Ayọ Ogunbanwo ni Abule-Iroko lọwọ tẹ ẹ.
 
O ni ọpọ igba l'awọn ti gbiyanju lati mu Desmond, ṣugbọn to n yọ boro mọ wọn lọwọ, ṣugbọn ti okete rẹ ko raaye boru mọ wọn lọwọ lọjọ kejila, oṣu keje, ọdun ti a wa yii.
 
O tẹsiwaju pe kete tọwọ ti tẹ Desmond, lo ti bẹrẹ sii jẹwọ pe goolu loun wa a ji ninu ile naa, ati pe awọn ibọn ọwọ oun loun n lo lati fi daabo bo ara oun.
 
Siwaju sii ni Yusuf tun sọ pe ki wọn too de ile ti Desmond n gbe, iyawo rẹ, Simbi Temitọpẹ Desmond ti sare ba a tọju mẹta ninu awọn ibọn to n lo, lai mọ pe ọkọ rẹ ti jẹwọ pe mẹrin ni.
 
O wa ni ọga awọn, Olusọji Ganzallo ti paṣẹ pe ki wọn lọ fa a le awọn ọlọpaaẹkun Agbado lọwọ, lati le tẹsiwaju iwadii lori ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI