Ọrẹ mẹrin to lu jibiti miliọnu meji aabọ naira foju ba ile-ẹjọ l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, July 7, 2023

Ọrẹ mẹrin to lu jibiti miliọnu meji aabọ naira foju ba ile-ẹjọ l'Ogun


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti f'oju awọn ọrẹ mẹrin kan, Nwusulor Philip, Sunday Basil, Mbam Stephen, ati Nwafor Solomon ba ile-ẹjọ Majisireeti to wa niluu Ọta, ipinlẹ naa, lori ẹsun ilọnilọwọgba ati ole jija.
 
Jibiti miliọnu meji ataabọ le diẹ (N2.6m) naira la gbọ pe awọn mẹrẹẹrin, pẹlu awọn miran ti wọn ti juba ehoro lu jibiti ẹ ninu ọdun ti a wa yii.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni Philip, ẹni ọdun mejidinlọgbọn; Basil, ẹni ọdun mejidinlọgbọn; Stephen, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn ati Sọlomọn ni Agbẹfọba E.O. Adaraloye foju wọn ba ile-ẹjọ.
 
Adaraloye, nigba to n fẹsun kan wọn, ṣalaye pe aarin ọjọ kin-in-ni, oṣu keji si ọgbọn ọjọ, oṣu kẹfa, ọdun yii lawọn eeyan yii lu jibiti ọhun lojule kin-in-ni, adugbo Ọbalewo, Iṣhaga niluu Ọta.
 
Ohun ti a gbọ ni pe, niṣe l'awọn eeyan yii n fi ẹtanjẹ gba owo, ti wọn si n pe ara wọn ni oṣiṣẹ ileeṣẹ Quest International Company, ati pe iṣẹ ori ayelujara ni wọn tun fi n gba owo lọwọ awọn eeyan.
 
Husanni Abdulrahman, Faisat Saidu, Yahaya Magaji, Sulaiman Usman, ati Shuaibu Saddam la gbọ pe wọn lọ fẹsun kan awọn eeyan naa lọdọ ọlọpaa, ko to di pe wọn foju wọn ba ile-ẹjọ.
 
Ẹsun yii ni wọn lo tako iwe ofin ọdaran ipinlẹ Ogun ti abala 390(9), 419, ati 516 ninu iwe naa, t'ọdun 2006.
 
Bo tilẹ jẹ pe awọn mẹrẹẹrin sọ pe awọn ko jẹbi pẹlu alaye, sibẹ Onidajọ A. O. Adeyẹmi sọ pe oun ko tii le gbọ ọrọ lẹnu wọn titi di ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun yii ti igbẹjọ miran yoo waye.
 
Onidajọ Adeyẹmi wa faaye silẹ fun beeli gbogbo wọn pẹlu miliọnu meji naira ati oniduro kọọkan ti wọon n san owo ori wọn deedee fun ijọba ipinlẹ Ogun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI