Mo kabamọ pe mo ṣiṣẹ fun APC - Ronkẹ Oṣhodi Oke kọminu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, July 7, 2023

Mo kabamọ pe mo ṣiṣẹ fun APC - Ronkẹ Oṣhodi Oke kọminu


Gbajugbaja oṣerebinrin Yoruba nni, Ibironke Ojo Anthony ti sọ pe oun kabamọ wi pe oun polongo ibo fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, paapaa nitori ohun to ṣẹlẹ lasiko ifẹshonuhan iwọde ti awọn ọdọ ṣe lati f'opin si ọlọpaa kogberegbe ti a mọ si SARS, iyẹn ENDSARS.
 
Ibironke Ojo, ẹni tọpọ awọn ololufẹ rẹ tun mọ si Ronke Oṣhodi Oke lo sọrọ naa lakoko ifọrọwerọ to ṣe pẹlu Chude Jideonwo lori ikanni ayelujara laipẹ yii.

O ni ọdun mẹjọ ti iṣakoso APC lo kọja lọ yii ko tẹ oun lọrun, ati pe wọn ko mu awọn ileri wọn ṣe, eyi to mu ki irẹwẹsi ọkan ba oun nigba to ya.

Siwaju sii lo sọ pe ohun to ṣẹlẹ nigba naa ba oun lọkan jẹ pupọ, nitori pe ọpọ awọn eeyan lo lọ sii, ti ọpọ ọdọ si farapa yannayanna, ṣugbọn ti APC sọ pe ko ri bẹẹ.
 
Nibẹ lo ti jẹwọ wi pe lotitọ loun polongo ibo fun ẹgbẹ APC lọdun naa lọhun, ati pe owo diẹ loun gba fun ipolongo idibo ọhun, to si ni idi ni pe oun ko wo ti owo, bi ko ṣe ti igbagbọ toun ni si ẹgbẹ naa, lai mọ pe ijakulẹ ni yoo pada ja si.
 
Oṣhodi Oke ni ohun to ṣẹlẹ lọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun 2020 lo jẹ koun sọ ireti nu patapata f'ẹgbẹ APC.
 
“Mo ro pe APC yoo mu Naijiria lọ siwaju sii ni, mo ro pe wọn yoo mu ileri rere wọn ṣẹ. Eyi to jẹ nigba ti a n polongo ibo fun wọn, mi o gba owo pupọ. Mi o wo ti owo nigba naa, mo n wo ti ohun ti yoo ṣẹlẹ lọjọ iwaju ni.
 
“Gbogbo ohun ti wọn n ṣe ni mo ro pe ọdun mẹjọ ko le to lati fi tun Naijiria ṣe. Gbogbo wa naa la mọ bẹẹ. Ṣugbọn nigba ti ifẹhọnuhan ENDSARS de, o ba mi lọkan jẹ gidi.

“Ọkan mi bajẹ nitori pe gomina wa n sọ ọrọ bii mẹta ti ko jọ ara wọn lẹẹkan naa. Wọn sọ pe wọn ko pa ẹnikẹni. Ṣugbọn bi eeyan kan ba ku, ṣe kii ṣe pe aadọta eeyan lo ti ku pẹlu eeyan kan ṣoṣo ọhun niyẹn. Awọn ti ẹni naa n fun lounjẹ, awọn obi ẹ ati awọn aburo ati ẹgbọn ẹ. O ba mi lọkan jẹ gidi. Mo kabamọ pe mo ṣiṣẹ fun wọn.”
 
Fọnran naa ree

 

 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI