Oriire nla! FUNAAB di ile-ẹkọ fasiti to dara ṣikeji ni Naijiria - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 1, 2023

Oriire nla! FUNAAB di ile-ẹkọ fasiti to dara ṣikeji ni Naijiria


Niṣe ni gbogbo awọn akẹkọọ, oṣiṣẹ, to fi mọ awọn alaṣẹ fasiti iṣẹ agbẹ ati ọgbin to wa niluu Abẹokuta, iyẹn Federal University of Agriculture, Abẹokuta (FUNAAB) gba ilu, ti wọn si n jo kaakiri, nigba ti wọn kede wọn gẹgẹ bi ile-ẹkọ fasiti to dara ṣikeji bayii lorileede Naijiria.
 
Fasiti naa to ti pe ọdun marundinlogoji ti wọn ti da a silẹ la gbọ pe ajọ to n ṣagbeyẹwo bi eto ẹkọ ṣe n lọ si nilẹ adulawọ, iyẹn Afrika, Sub-Saharan Africa University Rankings kede rẹ laipẹ yii.
 
Ajọ naa tun sọ pe ipo kẹrindinlọgbọn ni FUNAAB wa nile Afrika, iyẹn laaarin awọn akẹgbẹ rẹ, lori bi wọn ṣe n dagba sii lẹka eto ẹkọ wọn.
 
Bẹ o ba gbagbe, fasiti to le ni ẹgbẹ lọna igba ataabọ 258 lo wa lorileede Naijiria lonii, nibi ti FUNAAB ti wa ni ipo keji.
 
Lara awọn koko marun-un ti a gbọ pe ajọ naa n wo lati mu awọn fasiti to dara julọ ni bi wọn ṣe ṣee sunmọ ati iwa ododo, ipa ti wọn n o nilẹ Afrika, ọna ti wọn n gbe eto ẹkọ wọn gba, bi awọn akẹkọọ ṣe n ṣe daadaa si ati ọna ti wọn n gba pawo wọle ati bi wọn ṣe n na owo wọn (‘access and fairness’, ‘Africa impact’, ‘teaching skills’, ‘student engagement’ and ‘resources and finance’.)

Gbogbo awọn ọna wọnyi ni wọn sọ pe fasiti naa ti kaju oṣuwọn, ti wọn si labawọn rara, nigba ti wọn n kede b'awọn fasiti ṣe n ṣe si nilẹ Afrika, iyẹn lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹfa, ọdun 2023.
 
Ju gbogbo rẹ lọ, Giwa ile-ẹkọ fasiti naa, Ọjọgbọn Oluṣọla Babatunde Kẹhinde ti wa gbe oṣuba kare fun gbogbo awọn oṣiṣẹ ati akẹkọọ fasiti, fun bi wọn ṣe n ṣiṣẹ takuntaun lati rii pe wọn lewaju, pẹlu ileri wi pe oun yoo tubọ maa ṣe daadaa siwaju sii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI