Orileede Mali ni Eric ti ko ọta ibọn wọ Naijiria, o ni Onitsha l'ẹni to ran oun niṣẹ wa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, July 21, 2023

Orileede Mali ni Eric ti ko ọta ibọn wọ Naijiria, o ni Onitsha l'ẹni to ran oun niṣẹ wa


Ileeṣẹ ologun orileede yii ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ awọn kan ti wọn ko obitibiti ibọn ati ọta ibọn loriṣiriṣi wọ Naijiria, ati pe iwadii awọn ti n lọ lọwọ.
 
Agbegbe opopona Ajilete siluu Owode to wa nijọba ibilẹ Ariwa Yewa, ipinlẹ Ogun lọwọ ti tẹ awọn eeyan naa, ti wọn si ni ipinlẹ Anambra l'awọn n ko awọn eroja ogun naa lọ.
 
Wọn ni asiko ti awọn oṣiṣẹ ologun orileede yii ti wọn n ṣiṣẹ lagbegbe naa n awọn ọkọ to n kọja lọ wo, ni aṣiri tirela ti wọn fi ko awọn ibọn naa wọ Naijiria tu si wọn lọwọ.
 
Awọn oṣiṣẹ 192 Batalion la gbọ pe o rọwọ to awọn eeyan naa ninu tirela ti nọmba idanimọ rẹ jẹ ENU 697 XY.
 
Wọn ni ofifo ni tirela ọhun wa, ṣugbọon ti wọn ti tọju awọn ibọn ati ọta ibọn sinu mọto ọhun ki aṣiri ma ba a tu.
 
Lara awọn ohun ti wọn ba ninu tirela ọhun ni katọọnu ọta ibọn 720, ti wọn si ni katọọnu kọọkan ni ọta ibọn mẹẹdogun, ti gbogbo rẹ si jẹ ọta ibọn ẹgbẹrun mejdinlogun.
 
Yatọ si eyi, wọn tun ba 250 packets of live cartridges of pellet black (totaling 2,500 cartridges).
 
Ọmọ orileede Ghana to wa tirela naa tọwọ tẹ, Eric Seworvor, nigba to n ka boroborobo ṣalaye pe orileede Mali lawọon ti n ko ọta ibọn naa bọ, ti awọn si gba ọna Idiroko wọle lati maa lọ siluu Onitsha to wa n'ipinlẹ Anambra.
 
Eric sọ pe ẹni to ran wọn niṣẹ naa ko ni ohun meji to n ṣe bi ko ṣe tita ibọn ati ọta ibọn
 
Ileeṣẹ ologun ti wa jẹ ko di mimọ pe ẹmi ati dukia araalu jẹ awọn logun pupọ, fun idi eyi, awọn ko nii gba iwa buruku laaye.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI