Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ gendekunrin, ẹni ọdun mejilelọgbọn kan, Samson Sikiru lori ẹsun wi pe o fun iya rẹ lọrun pa lagbegbe Itanrin to wa niluu Ijẹbu-Ode, ipinlẹ Ogun.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe Samson fun iya rẹ to jẹ Wolii-obinrin lọrun pa loru ọjọ Aiku tii ṣe Sannde to kọja yii.
A gbọ pe aburo Samson ko si nile lasiko iṣẹlẹ ọhun, idi ree to fi raaye huwa buruku naa.
Lara awọn to fi iroyin ọhun to wa leti sọ pe o ti le lọdun marun-un ti Samson ti kuro nile, ti ko si dagbere fẹnikẹni, ṣugbọon lojiji lo tun pada de ni nnkan bi oṣu diẹ sẹyin.
Wọn ni bo ṣe de, fikan ran kan lo n ṣe pẹlu siga, igbo at'awọn egboogi oloro to n mu ni gbogbo igba.
Nibi ti imukumu Samson pọ de, wọn ni ọpọ igba ni mama Samson ti lọ fi ọrọ rẹ to awọn oṣiṣẹ eleto aabo leti, ti wọn si ti lọ gbe e lati kilọ fun un loriṣiriṣi.
Lẹyin gbogbo eyi, wọn ni Samson ko gbọ, sibẹ, o ṣi n tẹsiwaju lati maa mu awọn imukumu rẹ.
Ọkan lara awọn ara adugbo to ni ka f'orukọ bo oun laṣiri jẹ ko di mimọ pe oun ni Samson sare wa a ba laaarọ ọjọ Aiku, Sannde naa wi pe iya oun to jẹ Wolii yọ ṣubu, o si ti ku.
Ẹni naa ni boun at'awọn ti wọn jọ n gbe ṣe sare wọle lati wo nnkan to ṣẹlẹ, l'awọn ṣakiyesi wi pe niṣe ni Samson fun iya rẹ lọrun pa, pẹlu awọn apa ti wọn ri lọrun ati ẹsẹ oku naa.
Wọn ni ọwọ osi mama ọhun ti kan, bẹẹ ni wọn tun ri ẹjẹ lọwọ Samson, eyi to jẹ ki wọn mọ pe niṣe lo fun mama naa lọrun pa.
Igba ti wọn ri ohun to ṣẹlẹ yii la gbọ pe Samson fẹẹ na papa bora, ṣugbọn ti awọn eeyan tete mu, ti wọn si ni ko tete jẹwọ ohun ṣẹlẹ, bo tilẹ jẹ pe ko sọ otitọ fun wọn.
Wọn ni igbo ni Samson ṣẹṣẹ mu tan ko to pa mama rẹ danu.
AWIKONKO gbọ pe awọn ara agbegbe naa ti lọ fa Samson le awọn ọlọpaa lọwọ lati tẹsiwaju iwadii lori ẹ, bẹẹ la gbọ pe wọn ti gbe oku mama naa lọ si mọṣuari fun ayẹwo lati mọ iru iku to pa a.
No comments:
Post a Comment