Ọwọngogo: Ọpọ anfaani lo ṣi n bọ fun igbadun araalu ni Kwara - Gomina AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 26, 2023

Ọwọngogo: Ọpọ anfaani lo ṣi n bọ fun igbadun araalu ni Kwara - Gomina AbdulRazaq


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ fun gbogbo awọn ara ati olugbe ipinlẹ Kwara lati lọ f'ọkan ara wọn balẹ nitori pe ọpọ anfaani lo ti n bọ fun igbayegbadun wọn.
 
AbdulRazaq lo sọrọ naa ninu atẹjade ti akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye gbe jade lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, to si ni ijọba oun ti n gbe igbesẹ to yẹ lati ri i pe owo iranwọ ori epo t'ijọba apapọ yọ kuro, ko pa awọn araalu lara.

Ajakaye sọ pe ọjọ Aje, Mọnde ni gomina sọrọ naa, ati pe gomina jẹ ko di mimọ pe bi ijọba apapọ ba gbiyanju ọna abayọ miran lori owo iranwọ ori epo, akoba nla ni yoo jẹ f'awọn araalu.
 
O ni bi ijọba ba gbero lati tẹ owo, ki wọn si maa na le ori epo, yoo pa araalu lara pupọ.
 
AbdulRazaq wa f'idi rẹ mulẹ wi pe awọn yoo bẹrẹ oriṣiriṣi eto ti yoo maa ro araalu lagbara, fun idagbasoke eto ọrọ ara aje, eyi ti yoo jẹ ki araalu le farada ọwọngogo ti ko ni pẹ ẹ d'opin naa.
 
"A ti gbe iranwọ dide ni oriṣiriṣi ẹka, to fi mọ ẹka eto ilera, eto ẹkọ, okoowo ati ileeṣẹ kereje. Awọn ti ko ti i kan yoo jẹ anfaani laipẹ. A n bẹ yin wi pe ki ẹ ni suuru. A n ṣiṣẹ papọ pẹlu ijọba apapọ lati ri i pe idẹrun de ba araalu. Laipẹ, nnkan maa wa bo ṣe yẹ, o si maa yẹ wa."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI